Wọn ṣi n wa iyawo ile to pa ọkọ ẹ pẹlu omi gbigbona l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Titi ta a fi pari iroyin yii, ko ti i sẹni to gbọ mo ko o Ramọta Sọliu, iyawo ile to da omi gbigbona sọkọ ẹ lara ti ọkunrin naa si ku, iyẹn laduugbo Iyana Ilewo, nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, ipinlẹ Ogun. Awọn eeyan ọkọ to pa ṣi n wa a ni, wọn ko ti i ri i.

Ohun ti AKEDE AGBAYE gbọ ni pe ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, ni obinrin ti wọn n pe ni Ramọta yii gbe omi kana to ho daadaa, bomi naa ti ho yaaya lo sọ ọ kalẹ, to si yi i le ọkọ rẹ to n jẹ Bello Sọliu lori.

Ko sohun to fa eyi ju pe wọn ni Ramọta to ti bimọ meji fọkọ ẹ maa n febi pa ọkọ ọhun, ati ọmọ-ileekeu kan to n gbe lọdọ wọn, ọkọ si ti ba a wi lori iwa yii titi, obinrin naa ko yipada.

Aiyipada yii lo mu Bello pe awọn ẹbi rẹ, pe ki wọn waa ba oun ba iyawo oun sọrọ, ko yee febi pa ọmọ ọlọmọ to n kewu lọdọ oun ati oun paapaa.

Awọn ẹbi ọkọ to wa yii da si ọrọ naa, wọn parọwa fun Ramọta pe ko yee febi pa awọn to yẹ ko maa fun lounjẹ, nitori ojuṣe rẹ ni lati fun wọn lounjẹ lasiko to yẹ.

Ọkan ninu awọn aburo ọkọ ẹ torukọ tiẹ n jẹ Usman Sọliu ṣalaye pe Ramọta ko fesi kan bayii lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja tawọn waa ba a sọrọ naa.

O ni boya bawọn ṣe da si i dun mọ ọn tabi ko fẹ bẹẹ, iyawo awọn ko wi kinni kan bayii, ti kaluku fi gba ile rẹ lọ.

Afi bo ṣe di aarọ ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Satide, ti wọn ni Ramọta gbe omi kana, tawọn to ri i tiẹ ro pe o fẹẹ pogi tabi ro amala fọkọ ẹ ni. Aṣe niṣe lo fẹẹ da omi to ho buruku naa le ọkọ ẹ lori. O ti da a le ọkọ lori tan kawọn araale too mọ ohun to ṣe.

Awọn eeyan sọ pe omi ti Ramọta da le ọkọ ẹ lori naa lo to wakati kan lori ina ko too sọ ọ kalẹ,  bo si ṣe sọ ọ lo yi i le ọkọ rẹ lori.

Ariwo Bello lawọn eeyan gbọ lẹyin eyi, nigba ti wọn yoo fi kan an ninu ile, ara rẹ ti n bo torotoro latari omi gbigbona yii, iyawo rẹ to da a le lori si ra mọ aarin awọn eeyan, ibẹ lo gba sa lọ.

Wọn sare gbe Bello lọ sọsibitu kan ni Rounder, l’Abẹokuta, awọn iyẹn ko gba a, ni wọn ba gbe e lọ sibomi-in, ṣugbọn nigba to di ọjọ Iṣẹgun, ọkunrin naa dagbere faye.

Ọjọ keji ti Bello ku ni wọn sinku ẹ nilana ẹsin Islam, ṣugbọn ko ti i sẹni to gburoo iyawo to ṣeleṣu lẹyin ọkọ yii, wọn ṣi n wa Ramọta Sọliu, wọn o ti i ri i.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ọlọpaa Ogun sọ pe ootọ niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ. O loun naa gbọ ọ ti wọn n sọ ọ lori eto redio kan ni, ṣugbọn oun o ro pe wọn fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.

Oyeyẹmi lawọn yoo ṣewadii lori ẹ ṣa, lati mọ bo ba ṣe jẹ gan-an.

Leave a Reply