Wọn ṣi n wa ọmọọṣẹ Yahaya Bello tawọn agbebọn ji gbe

Monisọla Saka

Awọn agbebọn tẹni kan o mọ ti ji Arabinrin Comfort Alegẹ, ti i ṣe oludamọran pataki lori eto ẹkọ si gomina ana nipinlẹ Kogi, Yahya Bello, gbe.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ṣe sọ, Lọkọja, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa, ni wọn ti gbe obinrin yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karundinlogun, oṣu Karun-un yii.

Lasiko ti obinrin yii fẹẹ wa mọto wọnu ile ẹ ni awọn agbebọn ti wọn ni wọn ti n fọgbọn tọpasẹ rẹ bọ lati ita fi mọto tiwọn dina mọ ọn, ti wọn si ji i gbe lọ.

Lẹyin ti wọn ji i gbe tan, ni awọn ajinigbe ọhun ka fidio obinrin ọhun silẹ. Ninu fidio ti wọn fi ranṣẹ sawọn mọlẹbi ẹ yii ni wọn ti ni ko ba awọn eeyan ẹ atawọn to di ipo ijọba ipinlẹ naa mu sọrọ.

Owuyẹ kan to jẹ ọkan lara awọn mọlẹbi obinrin naa to ba awọn oniroyin sọrọ ni, “Laaarọ ti wọn jade, mọto wọn ni wọn lọọ tunṣe. Nigba ti a ko ri wọn lasiko to yẹ ki wọn ti dari wọle ni gbogbo wa ko ọkan soke.

Afi bi a ṣe ri fidio ibi ti wọn ti fi aṣọ di wọn loju, ti wọn n bẹ awọn eeyan pe ki wọn ṣaanu awọn, ki wọn ran awọn lọwọ, nitori wọn ti ji awọn gbe”.

Bo tilẹ jẹ pe Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, SP Williams Aya, toun naa fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe oun ko gbọ si ọrọ owo itusilẹ ti wọn ni awọn ajinigbe fẹẹ gba, ọkunrin to ba awọn oniroyin sọrọ, to ni ki wọn fi orukọ bo oun laṣiiri sọ pe owo ti ki i ṣe kekere lawọn to ji obinrin naa gbe n beere fun.

Alukooro ọlọpaa yii ni awọn ko dawọ duro latigba ti iroyin ijinigbe obinrin naa ti de etiigbọ awọn, gbogbo akitiyan lawọn si n ṣe lati doola rẹ laaye ati lalaafia.

 

Leave a Reply