Wọn ṣi n wa aṣọbode tawọn onifayawọ ji gbe nipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ti awọn aṣọbọde atawọn onifayawọ ti kọju ija sira wọn nitosi abule Ọlọrunlere, lagbegbe Alapoti, nijọba ibilẹ Ado-Odo, nipinlẹ Ogun, ni wọn ti n wa aṣọbọde kan, Taiwo Ọdẹyẹmi, wọn ko si ti i ri i titi ta a fi pari iroyin yii.

Ohun ti Alukoro Kọsitọọmu nipinlẹ Ogun, Hammed Bukoye Oloyede, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ keji iṣẹlẹ naa ti i ṣe ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin, oṣu kejila, ni pe lọjọ kẹta, oṣu yii, ni awọn oṣiṣẹ aṣọbọde pade ikọ onifayawọ to fẹẹ gbe irẹsi ilẹ okeere rẹpẹtẹ wọ agbegbe naa, wọn si n mura lati mu wọn.

O ni bawọn onifayawọ ṣe ri eyi ni wọn bẹrẹ si i yinbọn mọ awọn aṣọbode, awọn kọsitọọmu yii naa si n da a pada fun wọn.

Ṣugbọn pẹlu iranlọwọ awọn ọmọọta, ọwọ awọn onifayawọ ju tawọn kọsitọọmu lọ, niṣe ni awọn aṣọbode naa si yaa wa’bi kan fara pamọ si, ti wọn ranṣẹ pe awọn ṣọja atawọn eeyan wọn mi-in lati waa kun wọn lọwọ.  O kan jẹ pe kawọn iyẹn too de lawọn onifayawọ atawọn ọmọọta ti gbajọba, bo ṣe di pe wọn ba mọto awọn aṣọbode naa jẹ niyẹn. Nigba tawọn aṣọbode yoo fi boju wọle ni wọn ri i pe aṣọbode to n jẹ Taiwo Ọdẹyẹmi ti dawati, wọn ko ri ọkunrin dẹrẹba to n wa wọn naa mọ laarin wọn.

Ẹsẹkẹsẹ lo ti han sawọn aṣọbode naa pe ikọ onifayawọ to ba mọto awọn jẹ naa ni wọn gbe aṣọbode yii to fi dẹni ti wọn n wa.

Ohun to ṣẹlẹ yii ko ni i da ikọ aṣọbode duro lati ma ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi wọn ṣe wi, wọn tilẹ ni yoo mu kawọn bẹrẹ si i fi ọwọ to tun le ju bẹẹ lọ mu awọn onifayawọ ni.

Gbogbo ọna ni wọn n wa bayii lati ri aṣọbode to sọnu yii ri laaye, wọn si ni gbogbo ẹni to lọwọ ninu ikọlu ọtẹ yii yoo jẹ kisa iya bọwọ ofin ba to wọn.

Leave a Reply