Wọn ṣi n wa awọn arinrinajo mẹjọ ti wọn ji gbe ni Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Titi di ba a ṣe n sọ yii lawọn agbofinro atawọn ẹṣọ alaabo lẹlẹka-jẹka ṣi n wa awọn arinrinajo kan ti wọn lawọn agbebọn ji gbe lagbegbe Akoko lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

ALAROYE gbọ pe awọn arinrinajo ọhun ti wọn to bii mẹsan-an ni wọn n bọ lati ilu Abuja lasiko ti iṣẹlẹ yii waye.

Agbegbe Iṣua, laarin Ifira-Akoko si Ido-Ani, ni wọn lawọn Fulani ti fabọn yọ si wọn, ti wọn da wọn duro, ti wọn si fipa ko mẹjọ ninu wọn wọnu igbo lọ nigba ti ẹni kan yooku raaye sa mọ wọn lọwọ.

Awọn afurasi ajinigbe naa ti kan sawọn ẹbi awọn arinrinajo ọhun, ọgọrun-un miliọnu Naira ni wọn si n n beere fun lọwọ ẹni kọọkan wọn ki wọn too le tu wọn silẹ.

Ọga ọlọpaa teṣan Iṣua-Akoko, Ọgbẹni Olowoyọ Akinbọde, ni awọn ẹsọ alaabo pẹlu ìranlọwọ awọn fijilante ti bẹrẹ wiwa gbogbo inu aginju to wa lagbegbe naa, boya awọn ṣi le ri awọn ti wọn ji gbe naa gba pada lasiko.

O ni ọkọ Toyota Sienna to n gbe awọn arinrinajo naa bọ lati Abuja nikan lawọn ba nigba ti awọn kọkọ ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa, ti oun si ti paṣẹ pe ki wọn gbe bọọsi ọhun lọ si teṣan wọn.

Olowoyọ rọ awọn eeyan agbegbe naa lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọlọpaa, ki ọwọ le tete tẹ awọn oniṣẹẹbi naa, ki wọn si doola ẹmi awọn ẹni ẹlẹni ti wọn fi sahaamọ wọn.

Alaga afun-un-sọ nijọba ibilẹ Guusu Ila-Oorun Akoko, Ọgbẹni Yọmi Babatunde, fi ẹdun ọkan rẹ han lori iṣẹlẹ ọhun, o ni awọn araalu kan ti yọnda ara wọn lati dara pọ mọ awọn ẹṣọ alaabo to fẹẹ lọọ doola ẹmi awọn arinrinajo naa ninu igbo ti wọn ko wọn pamọ si.

O waa dupẹ lọwọ awọn ẹṣọ alaabo ipinlẹ Ondo fun iṣẹ ribiribi ti wọn n ṣe ki alaafia le jọba ni gbogbo agbegbe Akoko.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn ti gbiyanju ati ri ẹni kan gba pada ninu awọn ti wọn ji gbe. O fi kun un pe akitiyan awọn ọlọpaa ṣi n tẹsiwaju lati ri awọn yooku gba pada laaye.

 

Leave a Reply