Wọn ṣi n wa Ẹmia Bungudu, nipinlẹ Zamfara, tawọn agbebọn ji gbe

Faith Adebọla

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa Emir ilu Bungudu, Alaaji Hassan Attahiru, tawọn janduku agbebọn ti wọn n ṣoro bii agbọn nipinlẹ Zamfara ati lapa Oke Ọya ilẹ, ji gbe.

Nnkan bii aago mẹta aabọ irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, la gbọ pe awọn agbebọn naa lọọ rẹbuu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ atawọn ọkọ alaabo to tẹle e lọna marosẹ Abuja si Kaduna, wọn ṣina ibọn bolẹ, wọn si fipa da wọn duro nitosi ileeṣẹ Olam, to wa ni ati-wọ Kaduna.

Wọn wọ Ẹmia naa bọ silẹ, wọn si fibọn dari rẹ sori ọkada ti wọn gbe sitosi kan, ni wọn ba gbe olori ilu naa wọ’gbo lọ.

A gbọ pe niṣe ni Alaaji Attahiru n dari rele lati ilu Abuja, nibi to ti lọọ kopa ninu ipade pataki kan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ati ti Zamfara ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. Wọn lawọn o ti i gburo ibi ti wọn ji ọba alaye naa lọ, ṣugbọn awọn ti bẹrẹ iwadii lati tọpasẹ awọn ajinigbe agbebọn naa.

Leave a Reply