Wọn ṣi n wa Ọdunayọ Jẹgẹdẹ, nọọsi to sọnu pẹlu mọto tuntun n’Ileṣa

Aderounmu Kazeem

Ninu idaamu ọkan lawọn mọlebi obinrin nọọsi kan, Ọdunayọ Jẹgẹdẹ, ṣi wa bayii niluu Ileṣa nipinlẹ Ọṣun lori bi obinrin naa ṣe dagbere ibiiṣẹ, ṣugbọn ti wọn ko ri i ko pada wale titi di asiko yii.

Ọmọ ẹ, Comfort, to ba awọn oniroyin sọrọ ṣalaye wi pe, ibiiṣẹ ẹ ni Igbaye Maternity Centre, n’Ileṣa ni wọn ti ranṣẹ pe iya oun wi pe ẹni kan n rọbi lọwọ, o fẹẹ bimọ. O ni, alọ ẹ lawọn ri pẹlu mọto ayọkẹlẹ tuntun, Chevrolet to ṣẹṣẹ ra, ṣugbọn ti obirnin nọọsi naa ko de ibiiṣe ẹ, ti ko tun ti i pada sile titi di asiko yii.

Ẹni aadọta ọdun ni wọn pe e, ọjọ kejọ oṣu kẹwaa ọdun yii ni wọn lo ti jade kuro nile ẹ to wa ni Ilo Ẹlẹfọ n’Ileṣa, ṣugbọn ti wọn ko ri i pẹlu mọto ẹ to gbe jade, bẹẹ ni ko ti i gba nọmba idanimọ sara mọtọ ọhun paapaa.

Ọmọ yii fi kun un pe, gbogbo akitiyan awọn lati ba a sọrọ lori foonu ẹ ni ko so eso rere, nitori foonu ọhun ti ku patapata. Bẹẹ gẹgẹ lo sọ pe lojuẹsẹ lawọn ti fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti ni teṣan wọn to wa n’Ijẹbu-Jeṣa ati ni Ileṣa.

Ninu ọrọ ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun sọ lori iṣẹlẹ naa, Arabinrin Yẹmisi Ọpalọla, o lawọn ti gbọ si iṣẹlẹ ọhun, ati pe gbogbo awọn ẹka ileeṣẹ agbofinro to yẹ ko gbọ pata loun ti fọrọ ọhun to leti, ti oun si n reti aabọ wọn lori iwadii bọrọ naa ṣe jẹ.

 

 

Leave a Reply