Wọn ba ageku ara Iya Ganiya Elekuru ninu ile babalawo n’Ileefẹ

Florence Babaṣọla
Kayeefi lọrọ naa ṣi n jẹ fun awọn eeyan agbegbe Irẹmọ, niluu Ileefẹ, pẹlu bi wọn ̣ṣe ba ogulutu ara obinrin kan to n ta ekuru ti wọn n pe ni Iya Ganiyat ninu ile ti ẹnikan ti wọn lo n ṣiṣẹ babalawo rẹnti.
Bi ki i baa si ṣe ti awọn ọlọpaa atawọn sifu difẹnsi ti wọn tete debẹ, awọn ọdọ tinu n bi iba ti dana sun ile naa patapata.
ALAROYE gbọ pe lati agbegbe L. A Primary School, Alapata, niluu Mọdakẹkẹ  lobinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Oyebọde Latifat ti maa n kiri ekuru lọ siluu Ileefẹ lojoojumọ.
Kayeefi lo jẹ fun awọn eeyan Irẹmọ nigba ti wọn ṣakiyesi pe obinrin elekuru naa wọnu ile naa, ṣugbọn ti ko jade mọ, to si jẹ pe ọkunrin to n gbebẹ nikan lo jade sita.
Ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjlọ Àbámẹ́ta lawọn ọdọ naa ya wọnu ile ọhun, wọn si ri i pe wọn ti ge ori ati apa Iya Ganiya mejeeji. Bayii lawọn eeyan bẹrẹ si i ya lọ sibẹ lati foju gan-an-ni ohun to ṣẹlẹ.
Pẹlu itara lawọn ọdọ fi bẹrẹ si i ba gbogbo nnkan to wa ninu ile naa jẹ, ti wọn si fẹẹ dana sun un ko too di pe awọn ọlọpaa ‘A’ Division ni Moore pẹlu awọn Sifu Difẹnsi debẹ.
A gbọ pe awọn ọdọ ti bẹrẹ si i dọdẹ ọkunrin to n gbenu ile naa kaakiri ilu Ileefẹ bayii, wọn si ti ṣeleri pe ibikibi tọwọ ba ti ba a lawọn yoo ti gbe e de ago ọlọpaa.
A gbiyanju lati ba Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọrọ lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ariwo pọ nibi to wa.

Leave a Reply