Wọn ba oku Ṣalewa lẹyin ileewe kan ni Badagry

Aderounmu Kazeem

Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa nipinlẹ Eko, Muyiwa Adejọbi, ti rọ awọn obi Ṣalewa Adebọwale ti wọn pa, ki wọn tete fi ọrọ ọhun to ọlọpaa leti ki iwadii to peye le bẹrẹ ni kiakia.

Lẹyin ileewe kan ni wọn sọ pe wọn ti ba oku ọmọ ọdun mọkandinlogun ọhun lẹyin ti wọn ti n wa a lati ọjọ kọkanla oṣu kẹwaa ọdun yii.

Adugbo kan ti wọn n pe ni Igando, l’Ekoo, ni wọn sọ pe ọmọ yii ti n bọ to fi dawati laarin ibẹ sile wọn.

Ẹgbọn ẹ to ba awọn oniroyin sọrọ, Feyikẹmi, ṣalaye wi pe ọmọleewe Poli l’Ekoo ni Ṣalewa n ṣe, ati pe idanwo si ileewe awọn nọọsi lo lọọ ṣe lọjọ to kuro nile, ko too pade iku ojiji ọhun.

O ni bo to ṣe pari idanwo ẹ lo ti pe awọn nile wi pe oun ko ni i le wa sile mọ lọjọ yẹn nitori pe oun ko tete pari idanwo naa. Ọdọ ibatan ẹ to wa n’Igando ni wọn sọ pe o pada sun lọjọ naa.

Iya Ṣalewa ni tiẹ ti sọ fawọn oniroyin pe lẹyin ileewe kan ni Badagry lawọn ti ri oku ọmọ naa lẹyin tawọn ti wa a titi.

Lati fidi ọrọ ọhun mulẹ lọdọ awọn ọlọpaa, ohun ti agbẹnusọ wọn sọ ni pe ki awọn mọlebi ̀ọmọ ti wọn pa a yii lọọ fọrọ naa to teṣan ọlọpaa to wa laduugbo wọn leti, ki iwadii le bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa kiakia.

Leave a Reply