Wọn ba oku oludije sipo gomina Labour Party ninu yara ẹ l’Ekoo

Monisọla Saka

Ọkan ninu awọn oludije dupo gomina ninu ibo abẹle ti yoo waye nipinlẹ Imo laipẹ, Oloye Humphrey Anumudu, ti jade laye.

Ninu ile ẹ to wa nipinlẹ Eko, lọkunrin naa ti ki aye pe o digbooṣe lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, lẹyin to de lati ipade ẹgbẹ Labour Party, to waye lolu ile ẹgbẹ wọn to wa niluu Abuja.

Ilu Mbieri, to wa nijọba ibilẹ Mbaitoli, nipinlẹ Imo, ni oloogbe ti wa, ọna to si gba ku lẹyin ti wọn ba oku ẹ ninu ile ẹ yii mu kawọn mọlẹbi ṣapejuwe iku ẹ bii eyi to lọwọ aye ninu.

Ọkunrin oniṣowo pataki to lowo gidi lọwọ ọhun, to tun jẹ oloṣelu, ti n dupo gomina ipinlẹ naa lati ọdun 1998. Oun ni wọn lo gbegba oroke ninu ibo abẹle gomina ọdun 1998, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, ko too di pe wọn gbe tikẹẹti naa fun Achike Udenwa, to ṣe gomina nipinlẹ naa fun odidi ọdun mẹjọ, laarin ọdun 1999 si 2007. Latigba naa lo ti n dupo gomina ipinlẹ Imo, bakan naa lo tun gbegba ibo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Grand Alliance, APGA, ṣugbọn ti ko tun rọwọ mu nibẹ.

Lọdun 2019, ọkunrin yii lo le waju ninu awọn ti wọn n dupo gomina lẹgbẹ wọn. K o too faye silẹ, ọkunrin naa ti ra fọọmu oni miliọnu marundinlọgbọn Naira, lati fi dije funpo gomina ti yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Ọkunrin kan to sun mọ mọlẹbi naa, ṣugbọn ti ko fẹ ki wọn darukọ oun ṣalaye pe lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, lọkunrin oniṣowo mọto yii dagbere faye. O ni iku ọkunrin naa ba awọn lojiji, nitori Abuja lo ti ṣẹṣẹ dari de lọjọ ọhun.

Agba amofin ni oloogbe, oun si ni alaṣẹ ati apaṣẹ ileeṣẹ Globe Motors, lẹyin ti ẹgbọn ẹ, Willy Anumudu, to jẹ olori ileeṣẹ naa jade laye lọdun 2020, latari arun COVID-19.

Leave a Reply