Wọn ba oku ọmọ baalẹ at’obinrin kan nihooho ninu mọto n’Idiroko 

Adefunkẹ Adebiyi,  Abẹokuta

Ikọ fijilante So-Safe nipinlẹ Ogun, pẹlu ajọṣepọ awọn ọlọpaa. ti ri oku ọkunrin ati obinrin kan nihooho ninu mọto, n’Idiroko lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu kejila yii.

Alaye ti Mọruf Yusuf, Alukoro So-Safe, ṣe ninu atẹjade ti wọn fi sita ni pe lasiko tawọn n wọde kiri lọjọ naa, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ lawọn ri mọto ayọkẹlẹ Toyota Camry alawọ eeru to ni nọmba LND 223 BV ti wọn paaki pẹlu ifura.

Iwaju ile kan laduugbo Agọ Egun, n’Idiroko, nijọba ibilẹ Ipokia, ni mọto naa wa gẹgẹ bi wọn ṣe wi.

Nigba ti wọn yẹ inu ọkọ ọhun wo ni wọn ri i pe oku eeyan meji ti wọn wa nihooho lo wa nibẹ, ọkunrin ati obinrin kan.

Ninu ìwádìí ni wọn ti mọ pe Azeez Iliyas lọkunrin to ku sinu mọto naa n jẹ, ati pe ọmọ ọkan ninu awọn baalẹ agbegbe naa ni. Wọn ni ẹni ọdun mẹtadinlogoji ni Deborah, ọmọbinrin ti wọn ba pẹlu rẹ.

Awọn fijilante sọ pe iwadii n lọ lọwọ, awọn si pada ri aṣọ ọkùnrin to ku naa ninu gọta niwaju ile kan ti wọn fura pe ibẹ lobinrin to ku naa n gbe.

 

Teṣan ọlọpaa Idiroko ni wọn ko awọn oku meji naa lọ fun itẹsiwaju iwadii.

Leave a Reply