Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Oku ọmọbinrin kan ni wọn ba pade lẹgbẹẹ ṣọọsi nla kan to wa lagbegbe Oke-Ijẹbu, niluu Akurẹ, laaarọ kutukutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Oku ọmọbinrin ọhun ti ko sẹni to ti i mọ ibi to ti wa la ri ti wọn fi aṣọ funfun we, ti wọn si tun ko awọn nnkan mi-in si ẹgbẹ rẹ nitosi oju titi ti wọn tẹ ẹ si.
Ọkan ninu awọn to wa nibi iṣẹlẹ ọhun ta a fọrọ wa lẹnu wo ni ko sẹni to le sọ pato asiko ti wọn gbe oku ọmọbinrin ta a n sọrọ rẹ yii wa si agbegbe naa.
O ni akiyesi ti awọn ṣe ni pe o ṣee ṣe ko jẹ awọn ọmọ Yahoo kan ni wọn lo o, ti wọn si fi oru boju waa ju oku rẹ sibi tawọn eeyan ti ba a nigba ti ilẹ mọ.
Oku ọhun si wa nibẹ ti ko sẹni to ti i fọwọ kan an ni gbogbo asiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.