Wọn ba oku ọmọkunrin kan ninu kilaasi ileewe alakọọbẹrẹ l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Iyalẹnu nla lo jẹ fun ọpọ eeyan ti wọn sadeede to gbọ nipa bi wọn ṣe ba oku ọmọdekunrin kan ninu agbara ẹjẹ nihooho ninu kilaasi ileewe Saint Peter’s Anglican Primary School, to wa ni adugbo Igirigiri, ni agbegbe Odo-Ado, ni ilu Ado-Ekiti.

Okunrin ti ko sẹni to ti i mọ mọlẹbi rẹ yii ni wọn sadeede ba oku rẹ ninu kilaasi kan nileewe naa gẹgẹ bi akọroyin wa ṣe gbọ.

Awọn araadugbo ti ile-iwe ọhun wa ti wọn ba ALAROYE sọrọ ṣalaye pe ni kutukutu aarọ ọjọ naa, ni deede agogo meje aabọ ti awọn ọmọleewe ọhun de kilaasi ni wọn sadeede pariwo pe awọn ri oku ọmọdekunrin kan ninu kilaasi awọn. Kia ni awọn araadugbo naa jade sita lati wo oku ọmọkunrin naa.

Oku ọkunrin yii ni wọn sọ pe o wa nihooho ninu agbara ẹjẹ. A gbọ pe loju-ẹsẹ ni ọga agba ileewe naa ti lọọ fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa leti. Lẹyin iṣẹju diẹ lawọn ọlọpaa waa gbe oku ọmọkunrin naa kuro ninu ileewe yii.

Nigba ti ALAROYE de agbegbe ileewe naa lẹyin wakati diẹ ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ọgọọrọ awọn araadugbo naa la ri ti wọn duro ni meji-meji, ti wọn si n sọ nipa iku ọmọdekunrin ti ẹnikẹni ko ti i mọ ọhun.

Ọmọkunrin kan to ba wa sọrọ, Ajayi Ogunsusi, sọ pe sadeede loun gbọ ariwo awọn ọmọleewe naa, eleyii ti o fa a ti oun fi jade sita lati waa wo ohun to ṣẹlẹ.

Ọkunrin yii ni bo tilẹ jẹ pe ile oun sun mọ ileewe naa, sibẹ, oun ko gburoo ibọn, o ni o ni lati jẹ pe wọn gbe oku ọmọdekunrin naa si ileewe yii lẹyin ti wọn ti pa a tan nibi kan ni, o ni ki i ṣe ara agbegbe awọn rara.

Iku rẹ ti da jinnijinni silẹ laarin oluko ati awọn ọmọleewe naa.

Nigba ti ALAROYE de ọfiisi oga agba ileewe naa, wọn ni o ti wa lọdọ awọn ọlọpaa, awọn olukọ to ku ni awọn ko le sọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa nitori pe ọga awọn ko fun awọn laṣẹ lati sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o sọ pe ọga ileewe naa lo fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa to wa ni adugbo naa leti. O fi kun un pe wọn ti gbe   oku ọmọdekunrin naa lọ si ile igbokuu-si titi ti iwadii yoo fi pari lori ọrọ naa.

Leave a Reply