Wọn ba ori ati ọwọ eeyan lọwọ Ibrahim ati Wasiu ni Kwara, oogun owo ni wọn fẹẹ fi i ṣe

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Akolo ọlọpaa lawọn ọkunrin meji yii, Wasiu Omonose, ẹni ọdun marundinlogoji, ati ẹnikeji rẹ, Akanbi Ibrahim, ẹni ọdun mejilelọgbọn, wa bayii, ẹsun pe wọn ba ori ati ọwọ eeyan ninu ẹru wọn, ti wọn si ni oogun owo ni awọn fẹẹ fi i ṣe ni wọn tori ẹ mu wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Opopona marosẹ Oke-Oyi si Jẹbba, ni awọn agbofinro ti mu wọn ni nnkan bii aago mọkanla aabọ aarọ. Lasiko ti awọn ọlọpaa n ṣe ayẹwo awọn ọkọ to n kọja loju popo ni wọn kẹẹfin baagi kan ninu ọkọ awọn afurasi yii, wọn tu baagi naa, wọn si ba ori ati ọwọ eeyan ninu rẹ, wọn si jẹwọ pe ọdọ aafaa kan ni awọn n gbe e lọ niluu Ilọrin, ti yoo ba awọn fi ṣe oogun owo. Wọn tẹsiwaju pe ọmọ bibi ilu Sharẹ, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, ni awọn.
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Tuesday Assayomo, ti waa ṣekilọ pe ki gbogbo awọn ọdaran nipinlẹ naa tete wa ibi gba lọ, tori pe nnkan ko le rọgbọ fun wọn nipinlẹ naa mọ bayii, ati pe ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ kan to ba tẹ ofin loju yoo fimu kata ofin ijọba.
O fi kun un pe lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii lawọn afurasi mejeeji yoo fiju ba ile-ẹjọ.

Leave a Reply