Wọn ba ori oku tutu lọwọ Lekan l’Abẹokuta, o loun fẹẹ fi setutu ọla ni

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Adatan, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, ni baale ile kan, Ọgbẹni Lekan Akinyemi, wa bayii tawọn ọlọpaa ti n beee ọrọ lọwọ ẹ lori ori oku tutu ti wọn ka mọ ọn lọwọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii.

ALAROYE gbọ pe niṣe ni ọkunrin yii lọ si itẹ oku kan to wa lagbegbe Isalẹ-Itoko, l’Abẹokuta, to si ge ori oloogbe kan tawọn ẹbi rẹ ṣẹṣẹ sin sinu saare lọ.

Wọn ni Ọgbẹni Nojeem Balogun to n gbe lagbegbe Iyana Sẹlẹ, Car Wash, l’Abẹokuta, ti i ṣe ọkan lara awọn ọmọ oloogbe ti wọn ge ori baba wọn lọ lo lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti pe awọn kan waa hu oku baba awọn tawọn ṣẹṣẹ sin laipẹ yii jade, ti wọn si ge ori rẹ lọ. Nigba tawọn ọlọpaa maa bẹrẹ iwadii abẹnu wọn, wọn pada fọwọ ofin mu afurasi ọdaran ọhun pẹlu ori oloogbe naa lọwọ rẹ, ti ko si le ṣalaye ohun to fẹẹ lo ori tutu ti wọn ba lọwọ rẹ fun. Nigba tawọn agbofinro mu un de agọ wọn lo jẹwọ pe loootọ, oun loun ge ori oloogbe naa, ati pe etutu ọla loun fẹẹ lo o fun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, sọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, ni afurasi ọdaran ọhun lọọ hu iwa ti ko bofin mu naa, ṣugbọn ọwọ awọn agbofinro pada tẹ ẹ lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa yii, pẹlu ori oku tutu ọhun lọwọ rẹ.

Alukoro ni awọn n ṣewadi nipa iṣẹlẹ ọhun, awọn si maa foju afurasi ọdaran ọhun bale-ẹjọ lẹyin abọ iwadii awọn nipa rẹ.

Leave a Reply