Wọn da Iyaabeji duro sọsibitu foṣu mẹrin l’Ekiti, nitori ko rowo iṣẹ-abẹ to fi bimọ san

Taofeek Surdiq, Ado Ekiti

Oṣu kẹrin ree ti obinrin kan to bi ibeji, Funmilọla Ogundele, ti wa lọsibitu ijọba apapọ niluu Ado-Ekiti, oun paapaa ko si ti i le sọ ọjọ ti yoo kuro nibẹ, nitori awọn alaṣẹ ọsibitu naa lawọn ko ni i yọnda rẹ rara, afi to ba san idaji miliọnu naira, owo iṣẹ-abẹ to fi bi awọn ọmọ naa tawọn ṣe fun un.

Pẹlu omije loju ni Iyaabeji yii fi ṣalaye ara ẹ fakọroyin wa lọsẹ to kọja. Funmilọla, sọ pe ninu oṣu keji, ọdun 2021 yii, lọkọ oun gbe oun lọ sọsibitu jẹnẹra to wa n’Ido-Ekiti, lati bimọ.

O ni wọn sọ foun pe ibeji lo wa ninu oun, ati pe iṣẹ-abẹ nikan loun le fi bi awọn ọmọ naa, eyi yoo si na awọn ni idaji miliọnu naira.

Iyaabeji tẹsiwaju pe iṣẹ ọkada lọkọ oun n ṣe, ko si ni idaji miliọnu tawọn ọlọsibitu n beere. O ni ṣugbọn awọn alaṣẹ ọsibitu naa sọ pe awọn yoo ṣiṣẹ abẹ naa foun na bawọn ko tiẹ ti i sanwo, nitori ẹmi iya atawọn ọmọ ṣe pataki ju owo tawọn fẹẹ gba lọ.

Eyi lo ni o jẹ ki wọn ṣiṣẹ-abẹ naa ti wọn si gba ẹbi oun pẹlu irọrun, lo ba ku owo sisan.

Afi bi Baba Ibeji, ọkọ Funmilọla, to yẹ ko sanwo ṣe sa lọ bamubamu, iyawo rẹ sọ pe ọjọ toun bimọ naa loun ti ri i gbẹyin. O ni ko yọju sọsibitu mọ debi ti yoo waa sanwo igbẹbi oun, bo ṣe di pe awọn ara ọsibitu mu oun atawọn ejirẹ silẹ niyẹn, ti wọn ni awọn ko ni i kuro lọsibitu naa, afi lọjọ tawọn ba san gbese iṣẹ-abẹ ọhun nikan.

Koda, nibi to le de, Iyaabeji sọ pe wọn fi ẹni kan ti oun to n ṣọ oun ni, oun ko le rin bo ṣe wu oun lọsibitu naa rara.

Obinrin to ni iṣẹ telọ loun n ṣe tẹlẹ ni Osi-Ekiti naa waa rọ awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria lati ṣaanu oun. O ni ki wọn ba oun da idaji miliọnu ọhun ko pe, koun le raa

 

 

Leave a Reply