Wọn dajọ iku fun Musiliu l’Abẹokuta, ọrẹbinrin ẹ to gbe lọ sotẹẹli lo ku mọ ọn lọwọ 

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ogun ti dajọ iku fun ọkunrin mẹkaniiki kan torukọ ẹ n jẹ Musiliu Owólabí, ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) ti wọn lo pa ọrẹbinrin ẹ, Afusat Idowu, to si gbe oku ẹ lọ sile akọku, to sin in sibẹ, lai sọ fẹnikan.

Adajọ agba pata fun ipinlẹ Ogun, Adajọ Mosunmọla Dipẹolu, lo dajọ iku fun Musiliu l’Ọjọruu, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kejidinlogunlogun, oṣu yii.

Agbefọba, James Mafẹ, ṣalaye fun kootu pe lọjọ kin-in-ni, oṣu keji, ọdun 2018, Musiliu ati Afusa jọ lọ sotẹẹli lati gbadun ara wọn gẹgẹ bii ololufẹ, lagbegbe Camp, l’Abẹokuta.

Nigba ti wọn gbadun ara wọn tan ni Afusa bẹrẹ si i kigbe inu rirun gẹgẹ bi Mafẹ ṣe wi, ko si pẹ sigba naa lo bẹrẹ si i yọ ifoofo lẹnu.

Bo ṣe n yọ ifoofo lẹnu yii ni olujẹjọ gbe e wọnu mọto, wọn kuro lotẹẹli naa. Ṣugbọn nibi ti wọn ti n lọ lobinrin naa ti ku sinu mọto Musiliu.

Bi eyi ṣe ṣẹlẹ ni olujẹjọ ṣe ọrọ naa lokuu oru. Ile akọku kan lo gbe e wọ gẹgẹ bi agbefọba ṣe wi, nibẹ lo si sinku ale rẹ naa si lai jẹ ki ẹnikẹni mọ.

Awọn ẹbi oloogbe bẹrẹ si i wa a lẹyin to jade ti ko wale mọ. Aburo rẹ ọkunrin lo lọ si tesan ọlọpaa, to si ṣalaye fun wọn pe Bode Olude, l’Abẹokuta, lẹgbọn oun dagbere nigba to n jade nile lọjọ naa, ikomọ lo si loun fẹẹ lọọ ba wọn ṣe nibẹ to fi di pe ko pada wale mọ.

Pẹlu itọpinpin gidí, wọn wadii ẹni ti oloogbe naa ba sọrọ gbẹyin, wọn si ri i pe Musiliu Owolabi ni.

Nigba ti wọn mu olujẹjọ, o jẹwọ ninu akọsile rẹ, o si mu wọn lọ sibi to sin Afusa si.

Ọrọ yii de kóòtù, Musiliu yi ohun padà, o lóun ko jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun.

Ṣugbọn Adajọ agba Dipẹolu sọ pe gbogbo ẹri lo foju han pe Musiliu jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an, o si paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun un titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.

 

Leave a Reply