Wọn dumbu Alufaa ijọ Anglican bii ẹran, wọn tun dana sun mọto ẹ

Faith Adebọla

Alufaa ijọ Anglican Saint Andrew, Rẹfurẹndi Emeka Merenu, ti kagbako iku ojiji, awọn agbebọn kan ni wọn lọọ ka a mọle ninu agbala ileejọsin to n gbe, wọn dumbu rẹ bii ẹran lleya, wọn si tun dana sun ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, ni wọn ba sa lọ.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, niṣẹlẹ aburu naa waye, nigba tawọn agbebọn kan lọọ sakọlu si ṣọọṣi Anglican, niluu Ihitte-Ukwa, nijọba ibilẹ Orsu, nipinlẹ Imo.

Ba a ṣe gbọ latọdọ Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), ẹnikan to wa nitosi ibi tiṣẹlẹ naa ti waye sọ pe ‘bawọn agbebọn naa ṣe wọle ni wọn bẹrẹ si i fẹsun kan ojiṣẹ Ọlọrun naa pe oun lo lọọ ko awọn ṣọja wa lati daabo bo awọn ọmọ-ijọ rẹ ati awọn ọmọleewe ti wọn n ṣedanwo Wayẹẹki (WASSCE) aṣekagba wọn nileewe Anglican ti Alufaa ṣọọṣi naa n bojuto.

Lẹyin ti wọn ti dumbu ọkunrin naa tan ni wọn tun da bẹntiroolu si ọkọ ayọkẹlẹ rẹ to wa lagbala ṣọọṣi naa, wọn dana sun un guruguru.’

Ṣe ṣaaju asiko yii lawọn ẹgbẹ ajijangba IPOB ti kede pe kawọn eeyan atawọn ọmọleewe fidi mọle wọn lawọn ọjọ pato kan ti wọn kede rẹ, wọn lawọn n fi isemọle naa daro olori wọn, Nnamdi Kanu, ati awọn yooku rẹ tijọba mu satimọle lori ẹsun pe wọn ko ẹgbẹ ti ko bofin mu jọ, wọn si fẹẹ doju ijọba de.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo, Ọgbẹni Micheal Abattam, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni iwadii ti bẹrẹ lori ọrọ naa, awọn si ti bẹrẹ iṣẹ lati wa awọn oṣika ẹda naa lawakan, ki wọn le jiya to tọ si wọn.

Leave a Reply