Wọn dumbu ọlọdẹ meji to n ṣọ ileepo n’Iliṣan

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Niṣe lẹjẹ eeyan n ṣan nilẹ bii omi, bi aya eeyan ko ba si ki daadaa, tọhun ko ni i le wo oku awọn ọkunrin ọlọdẹ meji tawọn kan dumbu bii ẹran loru ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nibi ti wọn ti n ṣọ ileepo Total to wa nikorita Delabo,Iliṣan-Rẹmọ, nipinlẹ Ogun.

Awọn araadugbo wulẹ ji ni wọn rí í pe wahala ti de, iyẹn laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji, ti a wa yii,  wọn ji ba oku awọn ọlọdẹ meji ti wọn jẹ ẹya Igbo naa ninu agbara ẹjẹ wọn ni.

Ohun to ṣi n ṣe awọn eeyan ni kayeefi lori iṣẹlẹ yii ni pe ko si apẹẹrẹ idigunjale nileepo yii, awọn to dumbu awọn ọlọdẹ naa ko si mu kinni kan kuro nibẹ, ẹmi wọn nikan ni wọn gba lọ.

Ṣugbọn ole ki i jagba ko ma ṣe e loju firi, awọn eeyan n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ awọn ẹya Hausa kan lo pa awọn ọkunrin yii.

Wọn ni o ṣee ṣe ko jẹ nitori iṣẹlẹ ọjọ Ẹti to kọja, nibi tawọn Mọla kan ti yari pe awọn yoo dana sun teṣan ọlọpaa Iliṣan-Rẹmọ, nitori awọn agbofinro kọ lati yọnda awọn eeyan meji kan ti wọn fẹẹ ji ọkada awọn Hausa lọ n’Iliṣan.

Awọn to fẹẹ ji ọkada ọhun ko ti í rí ì jí tọwọ fi ba wọn, ti wọn ko wọn lọ si teṣan lọjọ Jimọ naa. Ṣugbọn niṣe lawọn Hausa kora wọn lọ siwaju teṣan ọlọpaa yii, ti wọn ni k’awọn ọlọpaa yọnda wọn fawọn, kawọn le da seria fun wọn funra awọn.

Awọn ọlọpaa ko gba, bẹẹ lawọn Mọla lawọn o ni i kuro nibẹ. Niṣe lawọn ọlọpaa bẹrẹ si i yinbọn soke lati le wọn lọ, ṣugbọn wọn ko tete kuro nibẹ.

Koda, ọjọ meji la gbọ pe awọn ọlọkada Hausa naa fi yanṣẹ lodi lori ọrọ yii, ti wọn ko gbe ero kankan.

Eyi lo fa a tawọn eeyan fi n sọ pe iku ojiji to pa awọn ọlọdẹ yii le ni nnkan i ṣe pẹlu awọn Hausa tinu n bi, wọn ni ọna tawọn ẹya Boko Haram n gba fi paayan niyẹn, didumbu ẹni bii ẹran.

Ṣugbọn awọn mi-in sọ pe ko jọra wọn rara, wọn ni iwadii awọn ọlọpaa nikan lo le fìdí ohun tó ṣẹlẹ mulẹ.

A gbiyanju lati gbọrọ lẹnu DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro olopaa ipinle Ogun, ṣugbọn nọmba rẹ ko lọ.

Leave a Reply