Wọn fa aworan ti wọn fi ki Aregbeṣọla ku oriire ọjọọbi ya l’Oṣogbo

Ko jọ pe wahala ‘iwọ lo ju mi, emi o ju ọ’ to n fojoojumọ waye ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun yoo rodo lọọ mumi ni kia o.

Ọrọ naa ti di egbinrin ọtẹ bayii, bi wọn ṣe n pa ọkan ni omi-in n ru jade.

Ọrọ ẹgbẹ (The Osun Progressive) TOS kan ti wọn ni gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Rauf Arẹgbẹṣọla, lo wa nidii idasilẹ rẹ ni wọn n sọ lọwọ, afi bo ṣe di ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti awọn kan ti ẹnikẹni ko ti i mọ bayii lọọ fa patako nla ti wọn ri si Old Garage, niluu Oṣogbo, lati ṣami ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹrinlelọgọta ti Arẹgbẹ dele aye ya, ti wọn si ba a jẹ patapata.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni wọn ri patako naa, nigba ti yoo si fi di aarọ ọjọ Aje, wọn ti fa gbogbo aworan to wa lara patako naa ya, o si ti di ofurugbada.

ALAROYE gbọ pe akọwe afun-n-ṣọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, Rasaq Salinsile, lo ri patako naa lati fi ki minisita feto ọrọ abẹle naa ku oriire ọjọọbi rẹ. Ọjọ Aiku ni wọn ri patako naa, awọn kan si ti ba gbogbo rẹ jẹ ko too di ọjọ keji.

Bẹ o ba gbagbe, awuyewuye to n lọ tẹlẹ ni ẹgbẹ kan ti wọn da silẹ nipinlẹ Ọṣun ti wọn pe ni The Osun Progressive (TOS) Ohun ti wọn lo fa eleyii ni pe alaga afun-n-ṣọ ẹgbẹ naa, Ọmọọba Gboyega Famọdun, ti ba ẹgbẹ naa jẹ, wọn ni ko si iṣọkan ati aṣọyepọ kankan ninu ẹgbẹ naa mọ, wọn ni iru wahala yii kan naa lo da silẹ lọdun 2018 to si fẹrẹ jẹ ki ẹgbẹ naa sọ ipo gomina nu nipinlẹ Ọṣun. Gbogbo awọn iwa yii ni wọn lo fa a tawọn majẹ-o-bajẹ yii fi lọọ da ẹgbẹ ti wọn pe ni onitẹsiwaju ti ipinlẹ Ọṣun yii silẹ.

Alaga ẹgbẹ tuntun yii, Adelọwọ Adebiyi, sọ lasiko ikojade ẹgbẹ naa ni Satide ọsẹ to kọja pe ki ẹgbẹ APC l’Ọṣun ma tun ko sinu wahala lasiko idibo gomina ọdun 2020 lawọn ṣe da ẹgbẹ naa silẹ.

Awọn eeyan nla nla to wa ninu ẹgbẹ oṣelu naa ni Minisita fun ọrọ abẹle nilẹ wa, Rauf Arẹgbẹṣọla, Alaaji Moshood Adeoti, olori ileegbimọ aṣofin Ọṣun tẹlẹ, Najeem Salam ati Gbenga Awosode.

Bakan naa ni wọn rọ gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Oloye Bisi Akande ati awọn agbaagba tọrọ ba kan lati kilọ fun Famọdun ki o ko ẹnu rẹ nijaanu, ko mọ iru ọrọ ti yoo maa sọ.

Leave a Reply

//alpidoveon.com/4/4998019
%d bloggers like this: