Wọn fabuku kan Pasitọ Tunde Bakare, “Pastor Ṣakabula” ni wọn n pe e bayii o

Ohun to ṣẹlẹ si Pasitọ Tunde Bakare, olori ijọ Latter Rain, lati ibẹrẹ ọsẹ yii, ko jọ pe iru rẹ ṣẹlẹ si i ri laye rẹ. Ẹni to ba de ori ẹrọ ayelujara ni yoo ri abuku oriṣiriṣi ti wọn fi n kan ọkunrin oniwaasu nla naa, ko si si ohun to fa a ju bo ṣe sọ ara rẹ di olugbeja ojiji fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lọjọ Aiku, Sande, yii lọ, ati bo ṣe fi gbogbo ẹnu bu awọn agbaagba Yoruba kan, to si sọ oko ọro buruku ranṣẹ si wọn.

Ọlọrun nikan lo mọ igba ti ọro naa ti n gbe Pasitọ Bakare ninu, ṣugbọn ni ọjọ Sannde to kọja, o fi ibinu sọrọ naa jade. O ni awọn agba Yoruba ti wọn n kiri igboro, ti wọn is n binu Aṣiwaju Tinubu, agba yẹyẹ lasan ni wọn, nitori ilara lo fẹẹ pa wọn ku. O ni wọn n lara Tinubu ni, ati pe ohun ti ọkunrin oloṣelu yii ti gbe ile aye rẹ se, awon agbaagba yii ko le ṣe e titi ti wọn yoo fi ku. Ohun to si n dun wọn niyen. Pasitọ Bakare ni wọn n binu Tinubu, wọn n pe e ni ọmo ilu Iragbiji, bẹẹ ni wọn ni ki i ṣe ọmọ Abibatu Mọgaji, pe ko si ohun to kan awọn agbalagba yii ninu iyẹn, nitori wọn ko mọ ohun ti oju Tinubu ri nigba to wa ni kekere.

Paripari rẹ ni pe Pasitọ naa ni wọn n bu Tinubu pe o ko owo ilu jẹ, o ni ki awọn agbaagba yii, tabi ẹni to ba fẹ naa lọọ ko owo tiẹ jẹ, ki wọn fi Tinubu lọrun silẹ o jare. O ni awọn agba yii ko ri ibi ko owo ilu jẹ, ohun to si n ka wọn lara ree ti wọn fi n sọrọ Tinubu laidaa. O ni ki awọn ọmọ ijọ oun wo oju awọn agbaagba naa daadaa o, Agba Ṣakabula lasan ni wọn.

Awọn ọro wọnyi lo ru awọn eeyan ninu soke si Pasitọ Bakare, kia ni  ori ẹrọ ayelujara si ti kun. Ohun ti awọn kan si kọkọ sọ nibẹ naa ni pe ki wọn ma pe ọkunrin naa ni Pasitọ Bakare mọ, Pasitọ Ṣakabula ni ki won maa pe e, nitori o ti fi iṣẹ Oluwa silẹ, oṣelu lo ku to n ṣe. Wọn ni bi awọn agbaagba kan ba wa ti wọn jẹ Agba Ṣakabula nitori ọrọ oṣelu, a jẹ pe Bakare funra rẹ, Pasitọ Ṣakabula ni, nitori lọdun to kọja ni Pasitọ yii ki Tinubu mọlẹ, to sọ fun gbogbo eeyan pe aṣiwaju ole ati akowojẹ ni, ati pe bo fẹ bo kọ, yoo pọ gbogbo owo to ji ko yii dandan.

Yatọ si eyi, ọpọ igba lo ti pe Tinubu ni ole, akowojẹ, ati ẹni ti ko yẹ ko di ipo gidi kan mu nilẹ yii. Bakare ni awọn ti wọn n pariwo kiri pe Tinubu lawọ, o n fun awọn eeyan lowo, ko mọ pe Tinubu ko lawọ, owo wọn to ji ko lo n pada na fun wọn, yoo si jiya ẹṣẹ rẹ bo ba ya. Ohun to ya awẹn eeyan lẹnu ree, pe Pasitọ Bakare to ti fi gbogbo ọjọ aye rẹ bu Tinubu, to n pe e lole, oun naa lo wa n sọ pe ki awọn agba Yoruba to ba n pe Tinubu lole naa lọọ jale tiwọn.

Ohun to jẹ ki ọgọọrọ awọn ọmọ Yoruba kaakiri agbaye bẹre si i kan Pasitọ Bakare labuku ree, ti wọn si n pariwo  pe ki ẹnikẹni ma pe e ni Pasito Bakare mọ o, Pasito Ṣakabula lorukọ rẹ tuntun.

Leave a Reply