Wọn fẹẹ bẹ awọn alalẹ sawọn to ji ọpa aṣẹ Ọba Eko gbe

Aderounmu Kazeem

Ẹbi Akinṣemọyin, l’Ekoo, ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn ọdọ kan ṣe ko ile Ọba Rilwan Akiolu, l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja yii, nibi ti wọn ti gbe ọpa aṣẹ Kabiyesi lọ.

Ọkan lara idile to maa n jọba nigboro Eko ni ẹbi Akinṣemọyin n ṣe, wọn si ti sọ pe awọn ko ni i la oju awọn silẹ, ki awọn janduku ba iṣẹṣe ilu Eko jẹ.

Ninu atẹjade ti Ọmọọba Salami Abisako ati Adeyẹmi Sarumi, fọwọ si ni wọn ti kọkọ lodi bi awọn ṣoja ṣe kọlu awọn eeyan ti wọn n ṣewọde ni too-geeti Lẹki, eyi to pada da wahala nla silẹ laarin ilu. Bakan naa ni wọn sọ pe awọn faramọ iwọde alaafia tawọn ọdọ kọkọ bẹrẹ, ko too di pe awọn janduku ja a gba mọ wọn lọwọ.

Wọn ni ohun abuku gbaa ni bi awọn janduku to n ṣewọde yii ko ṣe ri ibi meji lọ, to jẹ pe aafin Ọba Rilwan Akiolu, Olowo Eko, ni wọn gba lọ lagbegbe Idunganran, ti wọn si ko o lẹru, ti wọn tun gbe ọpa aṣẹ ọba alaye naa sa lọ.

Ni bayii, ẹbi Akinṣẹmọyin ti waa ke si Apena Oṣugbo, Ọpa ati Akala lati ṣeto aabo to nipọn lori Aafin Ọba Akiolu, ki ipo ọba Eko ma baa  dohun agbelẹhe.

Bẹẹ gẹgẹ ni wọn ti paṣẹ fun awọn to ji ọpa aṣẹ ọba Eko gbe lati da a pada ti wọn ko ba fẹẹ ri ija awọn alalẹ laarin wakati mẹrinlelogun.

 

 

One thought on “Wọn fẹẹ bẹ awọn alalẹ sawọn to ji ọpa aṣẹ Ọba Eko gbe

Leave a Reply