Wọn fẹẹ da ija Yoruba ati Ibo silẹ ni o

Ẹgbẹ awon agbaagba ilẹ Ibo ti wọn n pe ni Ohaneze ti sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe gba ahesọ kan to n lọ nigboro gbọ lori iwọde SARS, iyẹn ariwo ti awọn kan n pa kiri pe awọn ọmọ Ibo lo fẹe ba ilu Eko ati lẹ Yoruba jẹ. Ẹgbẹ naa ni ko sohun to jọ ọ. Aarẹ ẹgbẹ awọn agba ilẹ Ibo yii, Oloye John Nwodo lo sọro naa jade fura ẹ.

Baba naa ni oun ti n gbọ oriṣiriṣi ọrọ, bẹẹ ni awọn aṣaaju ilẹ Ibo paapaa n gbọ, bi awọn kan ti n gbe e kiri pe awọn Ibo lo wa nidii biba dukia Eko jẹ, nitori inu to n bi wọn si ilẹ Yoruba. O ni eyi ko le ri bẹẹ laye, nitori ipinlẹ Eko ati ilẹ Yoruba ni ọpọlọ ọmọ Ibo ti n ri jijẹ-mimu wọn, ti wọn si n gbe igbe-aye rere, bawo ni eeyan yoo waa ṣe ba ibi to ti n ri jijẹ ati mimu rẹ jẹ.

Nwodo ni ajọṣe to ti wa laarin awọn Yoruba ati Ibo lati ayebaye ko ni i jẹ ki iru eleyii ṣẹlẹ, o ji ipa ti Yoruba ko ninu irin-ajo oṣelu Oloye Nnamdi Azikiwe ko kere bẹẹ naa ni won ṣe atilẹyin to yẹ fun Ibo lasiko ogun Ojukwu, nitori gbogbo diukia to jẹ ti awọn Ibo ni wọn pada waa ba nilẹ Yoruba lẹyin ti ogun pari, ti ko sẹni to sọ dukia kankan di tiẹ laarin awọn aṣaaju Yoruba gbogbo.

Nwodo ni awom ti wọn n gbe ọrọ yii kiri mọ ohun ti wọn n ṣe, wọn kan fẹẹ fi da ija Ibo ati Yoruba silẹ lasan ni, bẹẹ ni ko si aṣaaju ilẹ Ibo kan to faramọ ọrọ ti Nnamdi Kanu, olori ẹgbẹ kan ti wọn n pe ara wọn ni ajijagbara ilẹ Biafra naa n sọ. O ni ki gbogbo ọmọ Yoruba gbọ o, ki awọn Ibo ti wọn wa nilẹ Yoruba naa si gbọ, pe ọrẹ nla ni wọn, ki wọn ma jẹ ki awọn ti wọn n gbe ahesọ kiri da aarin wọn ru, nitori awọn yẹn kan fẹe fi daja ẹlẹyamẹyaa silẹ ni.

Leave a Reply