Wọn fẹẹ dana sun Yusuf at’ọrẹ ẹ n’Ilọrin, pọọsi obinrin  kan ni wọn ja gba

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ileeṣẹ ọlọpaa ti wọ afurasi kan, Yusuf Isiak, toun pẹlu Rasaq Sikiru, ja pọọsi Ọladele Ruth to n gbe ni Iyana Olodo, lagbegbe Airport, niluu Ilọrin, gba lọ sile-ẹjọ Magisreeti.

Akọsilẹ ọlọpaa ṣalaye pe lasiko tawọn ọdọ kan n gbiyanju lati dana sun wọn lawọn ọlọpaa to wa ni tesan Adewọle doola wọn, ti wọn si wọ wọn lọ sile-ẹjọ.

Agbẹjọro ijọba, Innocent Ọwọọla, sọ fun ile-ẹjọ pe Sikiru ko le foju bale-ẹjọ nitori pe o n gba itọju lọwọ nilewosan ọlọpaa.

O rọ ile-ẹjọ ko gbe Isiak sahaamọ ọgba ẹwọn nitori pe ẹsun ole ni wọn fi kan an, ki i ṣe eyi ti wọn le gba beeli rẹ ṣaa.

Ṣugbọn agbẹjọro olujẹjọ, Amofin Sulaiman, ni kile-ẹjọ ma ka ẹbẹ agbefọba naa si, o ni onibaara oun nilo itọju gidi nitori b’awọn araadugbo naa ṣe ṣe e baṣubaṣu.

Adajọ H.D Muhammed gba oniduuro olujẹjọ naa pẹlu ẹgbẹrun lọna igba naira ati oniduuro meji, o sun ẹjọ si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹta, ọdun yii.

Leave a Reply