‘’Wọn fẹẹ fawọn ounjẹ korona ti wọn ko pamọ ra ibo lọwọ araalu ni 2023 ni’’

Jide Alabi

Wọn ti ni yoo ṣoro fun ijọba lati maa tu ile awọn eeyan yẹbẹyẹbẹ lori bi ijọba ṣe sọ pe ẹni ti ko ba da ẹru to ji ko pada lasiko rogbodiyan SARS, awọn agbofinro yoo maa wọle waa mu wọn.

Wọn ni ile-ẹjọ nikan lo le fun iojọba niru aṣẹ bẹẹ, ati pe ẹnikẹni tawọn agbofinro ba kọlu ile ẹ lai ni iwe aṣẹ lati gbọn ile wọn wo yẹbẹyẹbẹ, iru ẹni bẹẹ le pe ijọba lẹjọ.

Amofin agba, Mike Ozekhome, lo sọrọ ọhun fawọn oniroyin. Ohun to sọ ni pe ti ijọba ba n sọ pe awọn araalu kan ji ẹru ijọba ko, kinni kan to ṣe pataki ni pe ti eeyan ba ji ẹru gbe, iwa ọdaran niyẹn, ṣugbọn yoo ṣoro fun ijọba ipinlẹ kan lati bẹrẹ si i ya ojule awọn eeyan lai ni iwe aṣẹ ile-ẹjọ lati ṣe bẹẹ lọwọ.

“Ohun ti ijọba gbọdọ ṣe ni pe o gbọdọ lọ sile-ẹjọ lati gbawe aṣẹ ko too le wọle ẹnikẹni, bẹẹ lo gbọdọ wa ninu iwe aṣẹ ọhun koko ohun ti wọn waa ṣe niru ile bẹẹ.”

O ni ohun itiju nla ni bi ijọba ṣe ko ounjẹ pamọ, ti ebi si n pa araalu gidigidi. Bakan naa lo sọ pe ainitiju lo n da ijọba laamu lori bo ṣe bọ sita, ti wọn si n pariwo pe gbogbo ounjẹ tawọn ko pamọ pata ni awọn araalu ti ji ko tan. Amofin yii fi kun un pe bẹẹ lounjẹ ti wọn ko pamọ yii, owo-ori ti araalu san ni wọn fi ko o jọ.

O ni, “Ebi, iṣẹ, oṣi lo wa orilẹ-ede yii, ati pe pupọ ninu awọn ọmọ Naijiria ni wọn ti sọ ireti nu paapaa, ti wọn ko si ni ireti gidi lori bi ọjọ ọla yoo ṣe ri. Ounjẹ ti wọn n ko pamọ yẹn, niṣe ni wọn fẹẹ tọju awọn ounje yẹn di ọdun 2023 lasiko ibo, ki wọn le pin in lati fi ra ibo lọwọ araalu.”

 

Leave a Reply