Wọn fẹẹ fi rogbodiyan to ṣẹlẹ l’Ekoo din agbara ilẹ Yoruba ku ni-Akeredolu

Faith Adebọla

Gomina ipinlẹ Ondo to tun jẹ alaga awọn gomina nilẹ Yoruba,  Arakunrin Ọlarotimi Akeredolu, ti sọ pe awọn kan ni wọn fẹẹ fi rogbodiyan to ṣẹlẹ niluu Eko din agbara ilẹ Yoruba ku ni.

Akeredolu to gba ẹnu awọn gomina ẹgbẹ sọrọ lẹyin abẹwo ti wọn ṣe si awọn ibi ti awọn ọmọọta bajẹ lasiko rogbodiyan naa lo sọrọ ọhun.

O ni afi bii oju ogun ni ipinlẹ Eko ri nigba ti awọn ṣe abẹwo kaakiri awọn ibi ti awọn janduku dana sun lasiko rogbodiyan naa. O waa pe fun iwadii to muna doko lori awọn to wa nidii bi dukia ijọba ati okoowo awọn eeyan ipinlẹ naa ṣe di ohun ti awọn kan n dana sun.

o ni, ‘‘O jẹ ohun ijọloju ati ẹdun ọkan fun wa bi awọn janduku yii ṣe lanfaani lati ba awọn nnkan ijọba, awọn ileesẹ, agọ ọlọpaa ati okoowo awọn eeyan wa jẹ pẹlu bi awọn ẹṣọ alaabo ṣe wa ni gbogbo agbegbe naa to. Iṣẹlẹ yii jẹ ka gbagbọ pe erongba mi-in wa lẹyin didana sun awọn dukia ijọba yii, awọn to ṣe e si ti mura rẹ silẹ, bẹẹ lawọn kan wa to n ti wọn lẹyin.

‘‘O jẹ ohun to kọ wa lominu pe lẹyin wakati mejidinlaaadọta ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, ti awọn kan ti wọn wọsọ ologun lọọ ṣakọlu si awọn ọdọ to n ṣewọde ni Lẹkki, ko ti i si ọrọ kankan lati ileeṣẹ ologun lori iṣẹlẹ naa. Ẹru tubọ waa ba wa gidigidi nigba ti gomina ipinlẹ Eko sọ pẹlu idaniloju pe oun ko ran awọn ṣọja lọ si ibi iṣẹlẹ Lekki naa, nitori ko si gomina to laṣẹ nilẹ yii lati ko awọn ṣọja jade lọ sibikibi.’’

One thought on “Wọn fẹẹ fi rogbodiyan to ṣẹlẹ l’Ekoo din agbara ilẹ Yoruba ku ni-Akeredolu

  1. Odale ile yoruba ni gbogbo yin pata. Ifa tisowipe ti eyan ba n yo ile da ohun buburu amayoruwonse ni oro eyin oselu ile yoruba. Gbogbo yin ni kielo ronu si ibiti eba ile babanlaku yinje de. Awon omo tiyin na aba orirunyije ni lagbara olorun

Leave a Reply