Wọn fẹẹ gbe ọmọ ti wọn ji lati ilẹ Benin wọ Kwara, inu posi ni wọn tọju ẹ si

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ajọ ẹsọ alaabo NSCDC, ẹsọ alaabo aṣọbode ati ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, ni wọn doola ẹmi ọmọdekunrin ẹni ọdun mejila kan kuro lọwọ awọn afurasi ajinigbe. Ẹnubode ipinlẹ Kwara si ti orilẹ-ede Olominira Benin ni wọn ti mu wọn.

Alukoro ajọ ẹsọ alaabo NSCDC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afolabi lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade kan to tẹ ALAROYE, lọwọ n’llọrin, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii. O sọ pe lasiko ti ajọ NSCDC, ẹsọ aṣọbode ati awọn agbofinro wa lẹnubode, ni awọn ri ọkọ kan ti wọn kọ nnkan kan si ara rẹ, bi awọn ṣe da ọkọ naa duro ni dẹrẹba to wa ọkọ ati ẹni keji rẹ ba ẹsẹ wọn sọrọ, ṣugbọn nigba ti awọn ṣe ayẹwo ọkọ naa daadaa lawọn ri posi ninu rẹ, awọn ṣi posi naa soke, awọn si ba ọmọdekunrin naa ti wọn we e lasọ funfun ninu posi, ti awọn si gbe ọmọ naa jade.

Afọlabi tẹsiwaju pe nigba ti awọn ọmọ kuro ninu posi awọn ṣe ayẹwo fun un, ti awọn si ri i pe ọmọ naa wa ni alaafia ara. Orilẹ-ede Olominira Benin ni wọn ti ji ọmọ naa gbe. O ni gbogbo igbiyanju awọn ẹsọ alaabo lati mu awọn ọdaran naa lo ja si pabo.

Ni bayii, Afọlabi ni awọn ti fa ọmọ naa le awọn ọlọpaa orile-ede Olominira Benin lọwọ fun iwadii to peye, ti ọmọ naa si ti darapọ mọ awọn ẹbi rẹ.

Leave a Reply