Wọn fẹsun buruku kan Purofẹsọ ọmọ Yoruba, wọn lo gbowo lọwọ awọn afẹmiṣofo

Wọn ti fi ẹsun buruku kan Purofẹsọ ọmọ Yoruba kan o, Ishaq Akintọla ti yunifasiti LASU, wọn lo n gbowo lọwọ awọn ọmọ ogun afẹmiṣofo ti wọn n daamu aye. Ọjọgbọn Akintọla ni olori ẹgbẹ ẹlẹsin kan to pe ni MURIC, ẹgbẹ to sọ pe oun fi n ja fun ẹtọ awọn musulumi ni Naijiria ni. Ṣugbọn igbimọ agbaye kan to n gbogun ti  ọrọ awọn afẹmiṣofo yii sọ niluu Abidjan lọsẹ to kọja yii pe ẹgbẹ afẹmiṣofo to buru ju lọ laye, ẹka ti West Afrika (ISWAP), ti gbe owo nla kan fawọn MURIC.

Ọgbẹni San Lous Keita, ẹni ti i ṣe ọkan ninu awọn ọmọ igbimọ agbaye ti wọn n pe ni Sahara Strategy Group (SSG), ti wọn ko ni iṣẹ meji ti wọn n ṣe ju ọna lati gbogun ti awọn afẹmiṣofo lọ, lo tu aṣiri ọrọ yii fun awọn ọmọ igbimọ to ku nibi ipade wọn, nibẹ lọrọ naa si ti kari aye. Ọmọ orilẹ-ede Mali ni Keita, olori awọn ọtẹlẹmuyẹn ibẹ si ni nigba kan. Ohun to jẹ ki ọrọ rẹ tẹ̀wọ̀n, ti ọpọ eeyan si gba a gbọ, niyi.

Ọkunrin naa sọ nibi ipade wọn naa pe aṣiri to tu si awọn lọwọ nibi iwadii ti awọn n ṣe lori ọrọ awọn afẹmiṣofo nilẹ Afrika lawọn ti ri i pe awọn apani-lainidii ISWAP, ti wọn ti n da awọn eeyan laamu kiri aye, ti wọn si ti ba ọna kan wọ ilẹ Hausa lọhun-un, ti n fun MURIC, ẹgbẹ Akintọla, lowo lati bii ọdun meji sẹyin, ati pe owo ti won ti gba bayii ti le ni ẹgbẹrun lọna aadọta-le-nigba dọla ($250,000). Ohun ti wọn sọ pe wọn ni ki Akintọla fi owo naa ṣe ni lati fi ko awọn ọmọ ogun afẹmiṣofo jọ̀ ni ilẹ Yoruba, ki wọn le mura silẹ fun ogun ti awọn apaayan naa yoo gbe ja guusu (South) ilẹ Naijiria laipẹ rara.

Lati igba ti iroyin yii ti jade lawọn eeyan ti n pe ijọba apapọ lọtun-un losi, pe ki wọn mu ọkunrin olori MURIC yii ko waa ṣalaye bi ọrọ ba ti jẹ, ko ma di ohun ti yoo ko wahala ba gbogbo ọmọ orilẹ-ede yii bo ba ya.

Awọn ọmọ ogun afẹmiṣofo ti fẹsẹ mulẹ nilẹ Hausa, iroyin ibẹru to si n jade ni pe wọn n bọ nilẹ Yoruba laipẹ jọjọ, ṣugbọn ko sẹni to mọ ọna ti wọn fẹẹ ba wọle, ni iroyin ọrọ Akintọla ati MURIC rẹ yii ṣe mu ijaya nla wa fun gbogbo ẹni to gbọ ọ.

One thought on “Wọn fẹsun buruku kan Purofẹsọ ọmọ Yoruba, wọn lo gbowo lọwọ awọn afẹmiṣofo

Leave a Reply