Wọn fofin de akẹkọọ ileewe imọ ofin to gbe ike omi sẹnu

Monisọla Saka

Ile ẹkọ imọ ofin ilẹ wa (Nigerian Law school), ẹka ti ipinlẹ Eko, ti bẹrẹ iwadii lori akẹkọọ kan ti wọn lo dori ike kọ ọna ọfun rẹ, to fi mu omi lasiko ti wọn n jẹun alẹ (dinner) ile ẹkọ naa lọwọ. Wọn ni igbesẹ naa lodi si ofin ati ilana ileewe ọhun.
O ṣee ṣe ki ile-ẹkọ fi ofin de e tabi ki wọn da a duro fungba diẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an yii.
Arakunrin kan to pe ara ẹ ni Zaid lo gbe iwe ‘waa wi tẹnu ẹ’ (query) ti ileewe naa fun akẹkọọ ọhun sori ẹrọ alatagba Twitter. Wọn ni akẹkọọ ọhun tasẹ agẹrẹ si ofin ẹlẹẹkẹfa, ẹsẹ ikọkandinlọgbọn to n ri si ihuwasi awọn akẹkọọ ile ẹkọ nipa imọ ofin lori iṣesi ati ihuwasi nibi ounjẹ alẹ to pọn dandan nileewe ọhun ti wọn n pe ni dinner.
Ninu lẹta ọhun ni wọn ti kọ ọ pe, “O ti de etiigbọ oludari agba ati olori fun ẹka eto ẹkọ pe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 ta a wa yii, lakooko ti wọn n jẹ ounjẹ alẹ lọwọ, ni gbọngan ijẹun, ni wọn ri i pe o n gbe ike omi sẹnu mu omi nigba ti kọọbu imumi wa niwaju rẹ ti o le lo.
Lẹta ti ẹnikan ti wọn n pe ni Fagbemi Charles-Titilayọ buwọlu lorukọ adari ati olori ẹka ẹkọ tun tẹsiwaju pe, “Fun iwa ti o hu yii, a n pe ọ lati waa ṣalaye idi ti o fi ro pe ko yẹ ki wọn da ṣẹria fun ọ lori ofin kẹfa to wa fun iṣesi ati ihuwasi nidii ounjẹ fawọn akẹkọọ imọ ofin ilẹ Naijiria ti o lu.
‘‘O gbọdọ fi alaye ati idahun rẹ ranṣẹ si adari ati olori ẹka ẹkọ laarin wakati mẹrinlelogun”.

Idaluu niṣelu, bẹẹ loootọ ati lododo, iṣe wọn nileewe ẹkọ imọ ofin, ti o si jẹ kan-n-pa ni pe awọn akẹkọọ imọ ofin gbọdọ jẹ ounjẹ ti wọn n pe ni dinner yii lẹẹmeji, ti ẹlẹẹkẹta si maa n waye lakooko ti wọn ba fẹẹ fun wọn niwee mo-yege.
Awọn akẹkọọ gbọdọ ti de gbọngan ijẹun, o pẹ tan, iṣẹju mẹwaa ki eto naa too bẹrẹ, bẹẹ ni gbogbo ibẹ yoo pa lọlọ.
O bẹrẹ lati ibi imura, titi kan ọna ti wọn n gba gbe ounjẹ sẹnu, bẹẹ ni wọn ki i sọrọ titi wọn yoo fi jẹun tan.
Wọn fi ẹsun kan arakunrin yii nitori pe wọn gbagbọ pe kọọbu imumi wa niwaju ẹ ko too waa dori ike omi kọ ọna ọfun, leyii to ta ko ofin wọn nile ẹkọ naa.

Leave a Reply