Wọn fọmọ ọdun mọkandinlogun lọkọ ni tipatipa l’Adamawa, lo ba gun ọkunrin naa pa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 Atimọle ọlọpaa ni ọmọbinrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Rumasau Muhammed, wa bayii, nipinlẹ Adamawa. Ọkọ to fẹ lọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ ọdun yii lo gun lọbẹ pa ti wọn fi mu un.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Adamawa, Suleiman Ngoroje, ṣalaye pe iwadii awọn fidi ẹ mulẹ, pe ọmọdebinrin yii ko nifẹẹ Muhammad Adamu, ọkọ rẹ ti wọn fipa mu un fẹ.

 O ni awọn obi iyawo yii ni wọn fipa ṣegbeyawo fun un pẹlu Muhammadu, ti wọn fa a fọkọ loṣu kẹjọ ọdun yii, nigba to si pe ọsẹ mẹta geerege ti wọn segbeyawo ọhun ni Rumasau gun ọkọ ẹ pa yii.

Lori idi to fi gun ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji naa pa, o ni iwadii fi han pe ọmọ ọdun mọkandinlogun naa ti n beere ikọsilẹ lọwọ ọkọ rẹ yii tipẹ, to n sọ pe oun ko nifẹẹ rẹ, ko jẹ kawọn tete kọ ara wọn. Ṣugbọn  ọkọ iyawo naa ki i gba, oun fẹẹ maa ṣọkọ Rumasau lọ ni.

Nigba to jọ pe Oloogbe ko ni i gba ki igbeyawo naa tuka ni iyawo fi ọbẹ gun un nikun labule Wuro Yanka, nijọba ibilẹ Shelleng, l’Adamawa ti wọn n gbe.

Ẹnikan to jẹ ọrẹ ọkọ, ti wọn pe orukọ ẹ ni Jophas Johnsley lo kọkọ mọ ohun to ṣẹlẹ nile awọn tọkọ-tiyawo naa, nigba ti wọn si gbe Muhammed lọ sọsibitu fun itọju to jẹ niṣe lo ku sọhun-un, iyẹn ni ọrẹ rẹ yii ṣe lọọ sọ fun wọn ni teṣan ọlọpaa, ti wọn fi waa mu iyawo to gun ọkọ rẹ pa naa.

Awọn ọlọpaa ṣi wa lẹnu ẹ, gẹgẹ bi Alukoro wọn l’Adamawa ṣe wi.

Leave a Reply