Wọn gbe Baba Ijẹṣa wa sile-ẹjọ, ladajọ ba ni ki wọn tun da a pada satimọle

Faith Adebọla, Eko

Lẹyin oṣu meji to ti wa lahaamọ awọn ọlọpaa latari ẹsun fifipa ba ọmọde ṣeṣekuṣe ti wọn fi kan an, gbajugbaja adẹrin-in-poṣonu onitiata ilẹ wa nni, Ọlanrewaju James Omiyinka, ti gbogbo eeyan mọ si Baba Ijẹṣa ti fara han niwaju adajọ, ṣugbọn niṣe ladajọ tun paṣẹ pe ko pada satimọle ọlọpaa.

Nnkan bii aago mejila ku iṣẹju mẹtadinlogun laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee yii, ni wọn gbe afurasi ọdaran naa de ile-ẹjọ Majisreeti to wa l’Ọpopona Birrel, lagbegbe Sabo, ni Yaba, nipinlẹ Eko. Aṣọ Polo olomi buluu kan lo wọn sori ṣokoto dudu ati salubata to wa lẹsẹ rẹ, bẹẹ lo wa lori ila pẹlu awọn afurasi ọdaran mi-in ti wọn waa jẹjọ ni kootu ọhun lọjọ naa. O mu iwe pelebe kan dani lede oyinbo, akọle ẹyin iwe naa ni “Bi o ṣe le rọwọ mu lasiko idaamu” (How To Thrive In Perilous Times).

O han pe ọkunrin naa ti ru, ko si le rin daadaa, lẹyin akoko diẹ to ti wa lori iduro, niṣe lo jokoo silẹẹlẹ gbagede kootu naa nigba ti igbẹjọ ko tete bẹrẹ.

Ọgọọrọ awọn oniroyin ati awọn mọlẹbi ni wọn wa nikalẹ nitori igbẹjọ ti wọn ti n foju sọna fun naa, bo tilẹ jẹ pe iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ kootu to n lọ lọwọ lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ko tete jẹ ki wọn gbe Baba Ijẹṣa rele-ẹjọ.

Nnkan bii aago kan ọsan ọjọ naa ni igbẹjọ bẹrẹ ni kootu ọhun, ẹjọ Baba Ijẹṣa si ni akọwe kootu naa kọkọ mẹnuba, ẹsun marun-un ni wọn fi kan an.

Lara awọn ẹsun naa ni pe o fọwọ pa ọmọde lara lọna aitọ, igbiyanju lati fipa ba ọmọde laṣepọ ati biba ọmọde laṣepọ. Wọn lawọn ẹsun naa ta ko isọri karundinlogoje (135), isọri kẹtadinlogoje (137), isọri ọtalerugba ati ẹyọ kan (261) si ọtalerugba o le mẹta (263), igba o le meji (202), iwe ofin iwa ọdaran todun 2015 tipinlẹ Eko n lo.

Ṣugbọn bi wọn ṣe mẹnuba awọn ẹsun naa tan, ti Baba Ijẹṣa si sọ pe oun ko jẹbi, ni agbẹjọro rẹ, Amofin Kayọde Ọlabiran, sọ pe oun ni ẹbẹ lati gbe siwaju Adajọ Peter E. Nwaka, adajọ si fun un laaye.

Agbẹjọro Baba Ijẹṣa bẹbẹ pe ki wọn fun onibaara oun ni beeli. O ni ti Adajọ naa ba wo ipo to wa bayii ni kootu, o han pe ara rẹ ko ya, o ni wọn ti ṣe e leṣe lẹsẹ debii pe niṣe l’ọkunrin naa n rin yẹnku-yẹnku, ko si le fẹsẹ rẹ duro daadaa. O ni awọn oogun kan tun wa to yẹ ko maa lo fun ailera rẹ lateyinwa, ṣugbọn ti ko ri oogun ati itọju gba latigba to ti wa lahaamọ. Tori naa, o parọwa pe kile-ẹjọ ṣiju aanu wo Baba Ijẹṣa, ki wọn jẹ kó maa tile waa jẹjọ rẹ.

Adajọ beere lọwọ agbefọba boya o fara mọ ẹbẹ olujẹjọ, ọkunrin naa fesi pe oun ko fara mọ ọn. O ni iru ẹbẹ yii ti waye nigba ti afurasi odaran naa wa lahaamọ, ṣugbọn ti wọn ko le pese awọn oniduuro ti wọn ni ki wọn mu wa, ati pe ajọ to n ba araalu ṣẹjọ, Directorate of Public Prosecution (DPP) ti mu ẹsun Baba Ijẹṣa lọ si kootu giga, iyẹn High Court, nipinlẹ Eko.

Lẹyin ti adajọ yiiri ọrọ naa wo, Ọgbẹni P. E. Nwaka ni labẹ ofin, niwọn igba ti ẹri ti wa pe wọn ti gbe ẹsun naa lọ si kootu giga, ẹjọ naa ti kọja ohun ti Majisreeti yoo tun maa gbọ niyẹn. O ni loootọ loun gbọ ẹbẹ olujẹjọ fun beeli, ṣugbọn bi ọrọ ṣe ri yii, oun ko lagbara mọ lati paṣẹ beeli fun un.

O ni ki wọn da Baba Ijẹṣa pada si atimọle ọlọpaa ni Panti, Yaba, ko si wa nibẹ titi di oṣu to n bọ ti igbẹjọ rẹ ṣee ṣe ko bẹrẹ nile-ẹjọ giga.

Leave a Reply