Wọn ti ileewe giga TASUED pa, nitori rogbodiyan awọn akẹkọọ ati ṣọja

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Latari rogbodiyan to ṣẹlẹ laarin awọn akẹkọọ Tai Solarin University of Education, Ijẹbu-Ode, pẹlu awọn ṣọja kan, eyi ti wọn tun gbe wọ ọjọ Ẹti, Furaidee, awọn alaṣẹ ileewe naa ti tilẹkun ibẹ, wọn ni ki gbogbo akẹkọọ gba ile awọn obi wọn lọ.

Ohun to kọkọ gbode ni pe awọn ṣọja ti gbe olori awọn akẹkọọ nileewe naa, Sọdiq Rabiu, lọ, pe wọn si tun gbe awọn akẹkọọ kan naa lọ pẹlu.

Wọn ni ohun to fa eyi ni pe awọn ṣọja naa da si ọrọ kan ti ko kan wọn, to jẹ o ni i ṣe pẹlu awọn akẹkọọ nikan ni. Oju ọna marosẹ Ṣagamu si Benin to gba ileewe TASUED kọja ni wọn ni awọn ṣọja naa ti ya bo awọn akẹkọọ ti ko ṣẹ wọn, iyẹn l’Ọjọbọ.

Agbegbe CONOIL gan-an ni wọn sọ pe awọn ṣọja yii duro si, ti wọn n mu awọn akẹkọọ, ti wọn si n sọ pe ki wọn san ẹgbẹrun lọna aadọta naira (50,000) lati gba ara wọn  silẹ.

Koda, atẹjade to kede eyi latọwọ olori akẹkọọ kan nileewe ọhun sọ pe awọn ti ko rowo naa fi gba ara wọn silẹ, niṣe lawọn ṣọja ko wọn lọ si bareke wọn. Wọn tun fi kun un pe wọn fẹrẹ lu olori awọn akẹkọọ pa.

Ọrọ naa di rogbodiyan, to bẹẹ ti awọn akẹkọọ yii ya si titi l’Ọjọbọ naa, ati laaarọ ọjọ Ẹti, ti wọn n kọrin pe eeyan meloo ni ṣọja yoo pa, afi ki wọn pa gbogbo awọn tan o, awọn ko ni i gba.

Nigba to di ọjọ Ẹti, atẹjade kan wa lati ọfiisi Alukoro ileewe TASUED, Abilekọ A. O Odubẹla. Ohun to wa nibẹ ni pe loootọ ni ija waye laarin awọn sọja atawọn akẹkọọ awọn, iyẹn loju ọna marosẹ Ṣagamu si Benin.

 

Wọn ni ọrọ naa de etiigbọ awọn alaṣẹ fasiti yii, pe wọn ti gbe awọn akẹkọọ kan lọ si bareke ṣọja to wa ni Ilese.

Odubẹla ṣalaye pe ẹsẹkẹsẹ lawọn alaṣẹ fasiti pe ọga agba ni bareke naa, o si ni loootọ ni awọn eeyan oun lọọ ṣiṣẹ loju ọna ọhun, oun yoo ri si ohun to ṣẹlẹ naa.

Alukoro waa sọ ọ di mimọ ninu atẹjade naa pe awọn ṣọja ko gbe akẹkọọ kankan lọ ninu ikọlu ọhun, wọn ko si yinbọn pa akẹkọọ kankan. Wọn lawọn ko ran ṣọja waa ba akẹkọọ ja, kawọn akẹkọọ naa ṣọ iwa wọn ki wọn si gba alaafia laaye.

Ṣugbọn nigba ti yoo tun fi di ọwọ ọsan, ti awọn alaṣẹ fasiti TASUED ṣepade pajawiri lọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹwaa, wọn gbe aṣẹ jade pe kawọn akẹkọọ fi inu ọgba silẹ, ki kaluku gba ile obi rẹ lọ.

Bakan naa ni wọn ni kawọn obi ri i daju pe wọn ba awọn ọmọ wọn sọrọ nipa ibi ti wọn ba wa lẹyin ikede naa, ki wọn si ri i daju pe wọn ti pada wale.

Ohun tawọn kan sọ ni pe ki i ṣe pe awọn ṣọja ji olori akẹkọọ gbe, wọn ranṣẹ pe e lori ọrọ naa, o lọọ jẹ wọn ni, iyẹn lo si pada ja si mimu ti wọn mu un sọdọ, ki i ṣe pe wọn ji i gbe.

Ṣugbọn lati dẹkun rogbodiyan mi-in to le tidi iṣẹlẹ yii yọ lawọn alaṣẹ ṣe tete ti ileewe pa.

ALAROYE ba akẹkọọ kan to jẹ ọlọdun keji nileewe naa sọrọ, alaye to ṣe ni pe awọn ṣọja naa gba foonu lọwọ awọn akẹkọọ kan, bẹẹ ni wọn tun gba mọto nidii awọn akẹgbẹ awọn mi-in. O ni iwa irẹjẹ yii lo mu awọn ya si titi tawọn fi di gbogbo ọna pa, tawọn si n kọrin pe awọn ko ni i gba.

Ọmọ to ni ka forukọ bo oun laṣiiri naa sọ pe nigba to ya, niṣe lawọn ṣọja bẹrẹ si i yin tajutaju sawọn, ti wọn n le awọn kiri ti wọn si n foju awọn gbolẹ.

O ni ohun to fa a ti rogbodiyan naa ko ṣe rọlẹ titi di ọjọ Ẹti ree, ko too di pe awọn alaṣẹ waa ti ileewe pa, bẹẹ, awọn n ṣedanwo lọwọ, awọn ti ọlọdun akọkọ ko si tilẹ ti i bẹrẹ tiwọn.

Ọjọ ti wọn yoo ṣi ileewe naa pada lawọn akẹkọọ n reti bayii, bẹẹ ni wọn n beere fun idajọ ododo lori ohun to ṣẹlẹ naa.

Leave a Reply