Wọn ji awọn oṣiṣẹ Inṣọransi meji gbe ni marosẹ Eko s’Ibadan

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022, ni Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fidi ẹ mulẹ pe loootọ lawọn kan ji awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Ma-dan-dofo ta a mọ si Inṣọransi gbe loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan. O ni meji lawọn ti wọn ji gbe naa.

Ọjọ Sannde ni wọn ji awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ Nigerian Council of Registered Brokers  (NCRIB), gbe nitosi Iṣara, nibi to jẹ ipẹkun ipinlẹ Ogun, loju ọna naa.

Aṣọ ologun lawọn ajinigbe naa wọ gẹgẹ ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago meje ku iṣẹju mẹẹẹdogun laaarọ si niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, iyẹn nigba ti mọto tawọn oṣiṣẹ yii n gbe bọ bajẹ sẹbaa ọna yii, ti wọn si sọkalẹ lati tun un ṣe.

Nibi ti wọn ti n ṣe mọto ọhun lawọn agbebọn to wọṣọ ologun naa ti jade wa lati inu igbo, bi wọn ṣe ko awọn eeyan meji yii wọgbo lọ niyẹn. Ibadan ni awọn oṣiṣẹ NCRIB yii ti n bọ, Eko ni wọn si n lọ ti wọn fi ji wọn gbe.

Akọwe ileeṣẹ yii, Tọpẹ Adaramọla, fidi ẹ mulẹ pe awọn ajinigbe ọhun ti pe. O ni foonu ọkan ninu awọn ti wọn ji gbe naa ni wọn fi pe ileeṣẹ NCRIB, ti wọn si n beere fun miliọnu lọna ogun naira fun ẹnikọọkan ki wọn too le tu wọn silẹ.

Adaramọla fi kun alaye ẹ pe awọn oṣiṣẹ onipo kekere lawọn ajinigbe naa ji yii, o ni wọn ko ti i di ọga rara lẹnu iṣẹ naa, koda, owo-oṣu wọn ko to ọgọta ẹgbẹrun rara.

Ṣugbọn Alukoro ọlọpaa Ogun lawọn ti wa lẹnu wiwa awọn eeyan naa, tawọn si n ṣiṣẹ takun-takun lati ri wọn gba pada.

 

Leave a Reply