Wọn ji ọlọpaa gbe ni Aba Tuntun, n’Ijẹbu-Igbo, wọn tun ba mọto wọn jẹ

Jide Alabi

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n wa ọlọpaa kan, Emmanuel Gene, ti awọn janduku kan ji gbe niluu Aba Tuntun, n’Ijẹbu-Igbo, ipinlẹ Ogun.

Ṣaaju asiko yii ni baalẹ ilu naa ti kọwe ẹsun si ileeṣẹ ọlọpaa pe awọn kan ninu ilu naa ni awọn nnkan ija oloro lọwọ, eyi ti wọn fi n ṣiṣẹ ibi lagbegbe naa.

ALAROYE gbọ pe ọlọpaa mẹẹẹdogun atawọn ẹṣọ fijilante bii marundinlogoji lawọn ọlọpaa ko lọ sinu ilu naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii.
Ọkan lara awọn eeyan ilu naa to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe ọpọlọpọ ibọn ni wọn ba lọwọ awọn janduku tọwọ ọlọpaa tẹ ọhun. Ibọn oyinbo mẹfa, ibọn ibilẹ mẹrindinlogun ati ọta ibọn bii mẹẹdogun.

Wọn ni lojiji ni wahala bẹ silẹ niluu Aba Tuntun, lasiko ti awọn ọlọpaa n mura lati kuro ninu ilu naa lẹyin tọwọ ti tẹ awọn eeyan kan pẹlu ohun ija oloro lọwọ. Awọn kan ninu ilu naa ni wọn sọ pe wọn kọ lu wọn, ti wọn bẹrẹ si i yinbọn, ninu eyi ti DPO, iyẹn ọga ọlọpaa to ko wọn wa atawọn ọlọpaa mi-in ti fara pa.

Ninu iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti ji ọlọpaa marun-un atawọn fijilante mẹta gbe, tawọn yooku si fẹsẹ fẹ ẹ.

Ibọn AK-47, atawọn ohun ija mi-in bii afẹfẹ tajutaju ni wọn ri gba lọwọ awọn ọlọpaa ti wọn ji gbe yii.
Ninu iwadii wa ni agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ti sọ pe lojuẹsẹ naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe ikọ ẹ dide lati lọọ gba awọn ọlọpaa ti wọn ji gbe ọhun silẹ, ninu eyi ti wọn ti ri mẹrin ninu wọn gba pada atawọn fijilante mẹta.  O ni awọn ṣi n wa Kọnsitebu Emmanuel Gene, to wa laahamọ awọn ajinigbe ọhun.
Siwaju si i, a gbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti tu awọn eeyan ti ọwọ tẹ lasiko laaṣigbo ọhun silẹ, bo tilẹ jẹ meji ninu mọto ọlọpaa ni awọn araalu ọhun bajẹ lasiko rogbodiyan ọhun.
Abimbola Oyeyemi  sọ pe afuarsi mẹta lo ti wa lọdọ awọn ọlọpaa bayii, nibi ti wọn ti n ran wọn lọwọ lori agbofinro ti awọn ṣi n wa.

 

Leave a Reply