Wọn ji olukọ Fasiti Akungba Akoko gbe loju ọna Akurẹ si Ikẹrẹ-Ekiti

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Olukọ Fasiti Adekunle Ajasin to wa l’Akungba Akoko, Ọgbẹni Mayọwa David Adinlẹwa, lawọn ajinigbe kan ji gbe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Ọgbẹni Adinlẹwa bọ sọwọ awọn onisẹẹbi ọhun lasiko to fẹẹ lọọ lo opin ọsẹ pẹlu iyawo atawọn ọmọ rẹ niluu Ikẹrẹ-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, nibi to fi ṣebugbe.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii, ni wọn lawọn ajinigbe ọhun ṣẹṣẹ gba ki ọkunrin naa ba iyawo rẹ sọrọ lẹyin bii ọjọ mẹta ti wọn ti gbe e wọ igbo lọ.

Bakan naa ni wọn tun pe awọn ẹbi rẹ sori aago lọjọ yii kan naa, ti wọn si ni wọn gbọdọ san miliọnu mẹwaa Naira ki awọn too tu u silẹ.

 

 

Leave a Reply