Wọn ka ibọn mọ Akinọla, ọmọ ẹgbẹ okunkun to fẹẹ da idanwo ru n’Igbẹsa lọwọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọmọleewe giga ‘Ogun State Institute of Technology,’ to wa n’Igbẹsa, nijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta, nipinlẹ Ogun, ni ọmọkunrin yii, Ojo Akinọla Iyanu.

Ṣugbọn awọn ọlọpaa ti mu un bayii, nitori wọn lo ti jẹwọ fawọn pe ọmọ ẹgbẹ okunkun AYE loun, idi si niyẹn toun fi nibọn lọwọ, toun si ṣe fẹẹ da idanwo ti wọn fẹẹ bẹrẹ nileewe naa ru, nitori oun ko ti i gbaradi fun idanwo ni toun.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa, lọwọ ba Ojo gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe wi.

Olobo lo ta teṣan ọlọpaa Igbẹsa, pe awọn akẹkọọ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun fẹẹ da idanwo ti wọn fẹẹ bẹrẹ lọjọ naa ru, nitori wọn lawọn ko ti i gbaradi ni tawọn, awọn ko si ti i fẹẹ jokoo ṣedanwo kankan.

Bẹẹ, o yẹ ki wọn ti ṣedanwo ọhun tẹlẹ, rogbodiyan to waye laarin awọn alaṣẹ ileewe atawọn akẹkọọ lo jẹ ki wọn sun un siwaju, ki wọn too pada ri ọrọ naa yanju, ti wọn si fẹẹ bẹrẹ lọjọ ti Akinọla ati ẹnikeji rẹ ti wọn pe ni Aloma, sọ ijangbọn kalẹ yii.

 Nigba tawọn ọlọpaa naa si ti gbọ ohun tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun fẹẹ ṣe, wọn mu awọn sifu difẹnsi, fijilante so-safe atawọn ẹṣọ ileewe naa mọra, wọn si jọ bẹrẹ si i yẹ awọn ọmọ to fẹẹ wọle ṣedanwo wo, lati ẹnu geeti abawọle ni wọn ti n yẹ wọn wo finni-finni.

Nibi ti wọn ti n yẹ wọn wo ni wọn ti gba baagi kan lọwọ Akiọnla ati ikeji rẹ, wọn jọ ni in ni. Bawọn agbofinro ṣe n yẹ baagi naa wo lọwọ ni ikeji Akinọla ti wọn n pe ni Aloma sa lọ ni tiẹ, lawọn ọlọpaa ba yaa sare mu Akinọla to ṣi duro.

Nigba ti wọn yẹ inu baagi naa wo, ibọn ilewọ ibilẹ kan ni wọn ba nibẹ, ọta ibọn ẹyọ kan ti wọn ko ti i yin si wa ninu ibọn ọhun.

Akinọla tọwọ ba yii jẹwọ fawọn ọlọpaa gẹgẹ bi wọn ṣe wi, o ni ọmọ ẹgbẹ okunkun AYE loun, gẹgẹ boun ṣe jẹ akẹkọọ nileewe naa.

O fi kun alaye ẹ pe oun atawọn ẹgbẹ oun pinnu lati da idanwo naa ru nitori awọn ko ti i gbaradi ni tawọn, ojiji ni idanwo yii ba awọn, nitori ẹ lawọn ko ṣe fẹ ko waye, tawọn ṣe fẹ ko daru ki kaluku gba ile iya rẹ lọ.

CP Lanre Bankọle ti ni ki wọn gbe e lọ sẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran, ki wọn si wa awọn yooku rẹ ti wọn jọ gbero aburu naa ri, ki wọn mu wọn ṣinkun lati jiya labẹ ofin.

 

Leave a Reply