Wọn ka Kamọru mọ’bi to ti n fipa ṣe ‘kinni’ fọmọ ọdun mẹwaa l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Diẹ lo ku ki wọn lu baba agbalagba kan pa nigba ti wọn ka a mọ ibi to ti n fipa ba ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹwaa kan lo pọ lagbegbe Danjuma, niluu Akurẹ, lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii.

Baba to ti to bii ọmọ aadọta ọdun naa lawọn ọdọ kan fẹẹ dana sun, ki awọn oṣiṣẹ ajọ sifu difẹnsi too gba a silẹ lọwọ wọn lọjọ naa.

Ninu alaye ti ọmọbinrin ta a forukọ bo laṣiiri naa ṣe fawọn eeyan to fọrọ wa a lẹnu wo, o ni o pẹ ti baba ọhun ti n le oun kiri lati fipa ṣe kinni foun, ṣugbọn ti oun n sa fun un.

O ni ibi toun atawọn ọrẹ oun kan ti n ṣere lọwọ baba naa ti tẹ oun lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, to si fi agbara fa oun lọ si ẹyinkule, nibi to ti bọ pata idi oun, to si n fi kinni rẹ gun oun labẹ.

Ọmọbinrin naa ni oun gbiyanju ati pariwo, ṣugbọn ṣe lo fọwọ di oun lẹnu pa kawọn eeyan ma baa gbọ.

Ninu ọrọ tirẹ, Kamọru jẹwọ pe loootọ loun bọ pata rẹ lati ṣe kinni fun un, ṣugbọn oun ko ti i debẹ rara toun fi dami ara, lai mọ pe omi ọhun tun da si ọmọdebinrin naa lara.

Ikawọ ajọ sifu difẹnsi lọkunrin naa ṣi wa ni gbogbo asiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.

 

 

Leave a Reply