Wọn ka ori oku mọ tọkọ-tiyawo lọwọ l’Odogbolu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Awọn gende mẹta tẹ ẹ n wo pẹlu obinrin kan to wa laarin wọn yii ni: Muyideen Tolubi, Ṣonubi Taiwo, Niyi Fọlọrunṣọ ati iyawo ẹ, Rẹmilẹkun Fọlọrunṣọ. Ori oku ni wọn gbe dani yii, wọn ti ge e kuro lara ẹni to ku naa kawọn ọlọpaa too mu wọn  l’Odogbolu, nipinlẹ Ogun.

 Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, ni olobo ta ẹkun ọlọpaa Odogbolu, lọdọ DPO, CSP Afọlabi Yusuf, pe awọn kan wa nibi kan niluu naa ti wọn n hu oku ninu saaree, bẹẹ wọn ko ba oku naa tan nibikibi.  

Awọn ọlọpaa debẹ loootọ, ṣugbọn awọn to n hu oku naa ti hu u tan, wọn si ti lọ. Eyi lo mu awọn agbofinro bẹrẹ itọpinpin to lagbara, lẹyin iwadii kikun naa ni ọwọ ba awọn tọkọ-tiyawo torukọ wọn n jẹ Niyi ati Rẹmilẹkun Fọlọrunṣọ yii, wọn si mu Muyideen Tolubi naa.

Awọn mẹtẹẹta yii jẹwọ pe awọn lawọn hu oku naa, tawọn si ge ori rẹ, awọn naa ni si wọn mu awọn ọtẹlẹmuyẹ lọ si Ikẹnnẹ, nibi ti ẹni kẹrin wọn to ni ki wọn wa ori eeyan wa naa n gbe.

Gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ṣe ṣalaye, o ni awọn mẹrẹẹrin ti jẹwọ pe awọn fẹẹ fi ori oku naa ṣe etutu ọla ni.

Ṣa, ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun, ti ni ki wọn taari tọkọ-taya to fẹẹ ṣoogun owo naa lọ sẹka SCID, ki wọn si ko awọn meji yooku naa lọ pẹlu.

Leave a Reply