Faith Adebọla, Eko
Ko jọ pe afurasi ọdaran, Sunday Akpa, tọwọ awọn agbofinro tẹ lagbegbe Iba, Ọjọọ, nipinlẹ Eko, lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, mọ pe iṣẹ buruku loun n ṣe, tori niṣe lo mu ole jija nirona loju paali, ibọn meji loun nikan ko dani to fi n ṣọṣẹ fawọn onimọto ati ero ọkọ.
Awọn ọlọpaa teṣan Iba ti wọn n ṣe patiroolu kiri agbegbe naa ni wọn kẹẹfin Sunday, ẹni ọdun mẹrinlelogun ọhun, nibi to ti n fibọn gba foonu ati owo lọwọ awọn ero ninu goo-si-loo, o si ti n bọ si wiriwiri ọjọ, ilẹ ti n ṣu, asiko tawọn oṣiṣẹ n dari rele ni.
Bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko ṣe wi, CSP Adekunle Ajiṣebutu, sọ pe bi jagunlabi ṣe ri awọn ọlọpaa lo ta kọṣọ sabẹ mọto kan to wa lẹgbẹẹ titi, nigba tawọn ọlọpaa si wọ ọ jade labẹ ọkọ naa, niṣe lo yọwọ ija si wọn, o loun o ṣe nnkan kan, kin ni wọn fẹẹ mu oun fun.
Ko pẹ tawọn ero ri eyi ni kaluku ba n pariwo pe ole ni, wọn lo ṣẹṣẹ yọ ibọn sawọn tan ni, awọn kan si fẹsun kan an pe o ti ja foonu awọn gba, ni wọn ba wọ ọ ju si mọto patiroolu awọn ọlọpaa naa.
Ni teṣan wọn, wọn tu apo to gbe kọpa wo, wọn ba ibọn pompo meji ninu baagi ọhun, wọn tun ba ọta ibọn rẹpẹtẹ ti wọn o ti i yin, oogun abẹnugọngọ, foonu ati ọbẹ aṣooro kan. Wọn lafurasi ọdaran naa ti jẹwọ pe awọn nnkan ti wọn ri yii, irinṣẹ oun ni, o ni iṣẹ ole jija loju popo loun n ṣe, ati pe ki i ṣe oun nikan o, ara ikọ ẹlẹni mẹta kan loun wa.
Wọn lo tun ṣalaye fawọn ọlọpaa pe agbegbe Festac si Mile 2, Ọjọọ de Alaba lawọn ti n ṣiṣẹ. O ni ko ti i ju oṣu marun-un lọ toun bẹrẹ iṣẹ gbewiri yii, awọn ọrẹ oun ni wọn si mu oun wọnu ikọ adigunjale toun wa.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe ki wọn taari Sunday si ẹka ọtẹlẹmuyẹ, o si ti balẹ sọdọ wọn. Iwadii ti n lọ lori ọrọ rẹ, wọn ni laipẹ lo maa kawọn pọnyin rojọ niwaju adajọ.