Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Obinrin kan, Oluwatoyin Adetọna, ti yọju siwaju igbimọ to n gbọ ẹsun iwakiwa awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun lati gba idajọ ododo lori bi ọlọpaa kan ti wọn lo ti muti yo ṣe ṣeku pa awọn ọmọ rẹ meji lọdun 2015.
Gẹgẹ bi obinrin naa ṣe sọ, “Aarọ ọjọ Sannde kan niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lọdun 2015, a n mura ṣọọsi lọwọ ni, mo wa ninu ileewẹ ni mo deede gbọ ariwo, nigba ti mo maa jade sita ile wa to wa ni D112, Ẹgbẹ Idi, niluu Ileṣa, oku meji lara awọn ọmọ mi ni mo n wo nilẹẹlẹ.
“Ohun ti mo mọ mọ niyẹn nitori loju-ẹsẹ ni mo daku lọ rangbọndan. Odidi oṣu kan ati ọjọ mẹta ni mo lo nileewosan Wesley Guild Hospital, ki iye mi too sọ pada.
“Nigba ti mo pada sile ni ẹnikan tọrọ naa ṣoju ẹ ṣalaye fun mi pe ọkunrin ọlọpaa kan torukọ rẹ n jẹ Agada muti yo, to si wa ọkọ akọtami (Armoured Tank), ibi to ti n ṣe balabala loju titi lo ti kọ lu awọn ọmọ mi mejeeji, to si pa wọn. Wọn ni awọn araadugbo ba igo bia to n mu niwaju mọto akọtami naa”
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, agbẹjọro fun awọn ọlọpaa, F. B. Osei, sọ fun igbimọ naa pe wọn ti yanju ọrọ ti obinrin naa gbe wa nitori ileeṣẹ ọlọpaa ti da ọkunrin Agada naa duro latigba iṣẹlẹ naa, bẹẹ ni wọn ti gbe iwe ẹsun rẹ lọ si ẹka eto idajọ nipinlẹ Ọṣun fun igbẹjọ.
Ṣugbọn Iyaafin Adetọna sọ pe loootọ loun gbọ pe wọn ti da Aguda duro lẹnu iṣẹ, ṣugbọn oun ko gbọ pe wọn ti gbe e lọ si kootu. Bakan naa ni agbẹjọro olupẹjọ, Abdulfatai Abdulsalam, sọ pe ẹka eto idajọ ko ti i gbe igbesẹ kankan lori ọrọ naa.
Alaga igbimọ naa, Adajọfẹyinti Akin Ọladimeji, waa paṣẹ fun Akọwe igbimọ, Kẹmi Bello, ẹni to tun jẹ ọga agba lẹka eto idajọ nipinlẹ Oṣun lati ṣewadii lori ohun to fa a ti wọn ko fi ti i gbe Agada lọ sile-ẹjọ.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkandinlogun, oṣu keji, ọdun yii.