Wọn lara Tinubu o tun ya o, o ti pada si London fun itọju

Faith Adebọla, Eko

Ọrọ kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara lasiko yii ni pe gbajugbaja Adari ẹgbẹ oṣelu APC (All Progressives Congress), Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti tẹkọ leti lọ siluu London, lorileede United Kingdom, fun itọju iṣegun bayii ati ayẹwo ilera rẹ.

Ba a ṣe gbọ, alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kin-in-ni yii, ni gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri naa wọ baaluu ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe, l’Abuja, to si kọri siluu London.

A gbọ pe bonkẹlẹ ni wọn ṣe irin-ajo naa, latari awuyewuye to ṣee ṣe ko waye tawọn eeyan ba gbọ pe ilera Tinubu to n palẹmọ ati dupo aarẹ lọdun 2023, ti tun yingin.

Tẹ o ba gbagbe, ko ti i ju oṣu mẹta sẹyin lọ ti Bọla Tinubu de pada si Naijiria lati London, lẹyin to ti lo ọpọ oṣu lọhun-un, latari iṣẹ abẹ ati itọju iṣegun ti wọn fun un, ọkunrin naa ni orunkun oun lo n da oun laamu ti wọn fi ṣiṣẹ abẹ foun.

Ko pẹ to de lo bẹrẹ si i lọ kaakiri, ti ahesọ si gbalẹ kan pe Tinubu n mura lati dupo aarẹ lẹyin ti iṣakoso Buhari ba tẹnu bọpo.

Nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin, lọjọ kẹwaa, oṣu kin-in-ni yii, ni Tinubu funra rẹ ṣiṣọ loju eegun ọrọ naa fawọn oniroyin pe oun ti lọọ fi to Aarẹ Muhammadu Buhari leti pe oun maa jade dupo aarẹ lọdun 2023, tori ko si ofin to sọ pe ki afọbajẹ ma jọba.

O tun loun ṣi maa ṣe ikede ni gbangba fawọn araalu, ṣugbọn asiko ko ti i to, tori oun ṣi n fikun lukun kaakiri orileede yii, oun si si n gbe gbogbo ọrọ naa yẹwo lọwọ ni.

Bi Tinubu ṣe sọrọ yii tan ni agbo oṣelu orileede yii bẹrẹ si i ho ṣọṣọ bii ọbẹ gbigbona, latari oniruuru ọrọ ati awuyewuye to gbode kan, bawọn eeyan ṣe n ṣatako, tawọn mi-in si n sọ ero ọkan wọn lori erongba baba naa, bẹẹ lawọn alatilẹyin rẹ n sọ pe ko maa jo niṣo.
Ọkan ninu ọrọ ti wọn n sọ tako Tinubu ni pe o ti darugbo, ilera rẹ ko si le gbe wahala ipo aarẹ, wọn ni ọjọ-ori ẹ ju ọdun mọkandinlaaadọrin to sọ p’oun jẹ lọ.

Ṣa, awọn kan ti sọ pe ilu London to lọ yii, o wulẹ lọọ fara nisinmi ni, ki i ṣe pe ilera rẹ mẹhẹ.

Leave a Reply