Wọn lawọn ajinigbe ti pa onileetura ati oṣiṣẹ ẹ ti wọn ji gbe l’Ogbomọṣọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn ajinigbe ti yìnbọn pa ọkunrin onileetura ti wọn ji gbe pelu ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ẹ.

ALAROYE gbọ pe nitori iṣẹlẹ yii nigboro ilu Ogbomọṣọ ti ṣe n daru lọwọlọwọ bayii fun bi awọn akẹkọọ Fasiti Ladoke Akintola University of Technology, (LAUTECH), to wa niluu naa ṣe n ṣe iwọde lati fẹhonu han nipa iṣẹlẹ naa.

Ta o ba gbagbe, lọjọ kọkandinlọgbọn (29), oṣu Keje, ọdun 2022 yii, ti i ṣe ọjọ Jimọ to kọja lawọn ọbayejẹ eeyan ọhun ji oludasilẹ ileetura to wa nitosi fasiti ilu Ogbomọṣọ naa, Ọgbẹni Olugbenga Owolabi, ati ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ẹ to n jẹ Ọpadele Rachael gbe.

Akẹkọọ fasiti LAUTECH, ni Rachael, ipele aṣekagba ẹkọ ẹ lo wa ko too di pe eto iyanṣẹlodi ẹgbẹ awọn olukọ fasiti nilẹ yii (ASUU) sọ ọ dẹni to wa iṣẹ sileetura Ọgbẹni Owolabi ko ma baa maa jokoo kalẹ sile lasan.

Lọjọ kẹta iṣẹlẹ yii, iyẹn ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lawọn ọdaju eeyan naa pe awọn ẹbi Ọgbẹni Owolabi ati ti Omidan Rachael pe ki wọn wa miliọnu lọna aadọta Naira wa ki awọn le yọnda eeyan wọn to wa nigbekun awọn.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lẹyin ti awọn afẹmiṣofo yii gba miliọnu marun-un Naira (N5m) lọwọ awọn ẹbi wọn tan ni wọn yinbọn pa wọn sinu igbo.

Koda, wọn lawọn ajinigbe ọhun yinbọn mọ ẹni to gun ọkada lọọ gbe owo naa pade wọn nibi ti wọn ni ki wọn ti gbowo pade awọn, ṣugbọn ori ko ọkunrin naa yọ, ti ibọn naa ko ba a nibi to lewu titi to fi ribi ba sa lọ mọ wọn lọwọ.

Amọ ṣaa, a ko ti i fidi ẹ mulẹ boya loootọ ni wọn ti pa ọkunrin onileetura naa pẹlu ọmọọṣẹ ẹ to jẹ akẹkọọ fasiti yii pẹlu bi aitiyan wa lati ba SP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ sọrọ ko ṣe ti i seso rere titi taa fi pari akojọ iroyin yii.

Leave a Reply