Wọn lawọn eleyii lu Samuel pa n’Iju-Ọta nitori foonu 

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kin-in-ni yii, lawọn ọlọpaa mu awọn gende mẹta yii, Ugo Obi, Chinonso Jude ati Chibuike Samson, lagbegbe Iju-Ọta, nipinlẹ Ogun. Ọmọkunrin kan, Samuel Ajibade, ni wọn ni wọn lu pa nitori foonu ti wọn ni ọmọ naa ji.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣalaye pe baba ọmọ ti wọn lu pa yii, Gbenga Ajibade,  lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Onipaanu, l’Ọta, pe awọn gende mẹ́ta yii fẹsun kan ọmọ oun pe o ji foonu meji, wọn si bẹrẹ si i lu u titi to fi daku mọ wọn lọwọ.

O ni wọn sare gbe e lọ si ọsibitu Jẹnẹra Ọta, ṣugbọn ko pẹ ti wọn gbe e debẹ lawọn dokita sọ pe o ti ku.

Awọn eeyan tinu n bi nigba ti wọn gbọ pe Samuel ti ku tilẹ ti fẹẹ fi lilu ba aye awọn ọmọ Ibo mẹta yii jẹ, ọpẹlọpẹ awọn ọlọ́pàá teṣan Onipaanu ti wọn tete debẹ ti wọn gba wọn silẹ. ti wọn si ko wọn lọ si teṣan.

Ẹka to n ri si ẹsun ipaniyan ni awọn mẹtẹẹta wa bayii, nitori ibẹ ni CP Edward Ajogun paṣẹ pe ki wọn ko wọn lọ fun itẹsiwaju iwadii. Wọn ti gbe oku Samuel Ajibade si mọṣuari.

Leave a Reply