Iru ki waa leleyii, wọn lawọn Fulani to sa kuro n’Igangan ti tun paayan mẹta n’Imẹkọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

O kere tan, eeyan mẹta ni wọn ku iku ojiji nibi kan ti wọn n pe ni Amule Ọlọgẹdẹ, n’Imẹkọ, ipinlẹ Ogun, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹfa, oṣu kẹfa, ọdun 2021.

Ohun ta a gbọ ni pe awọn Fulani to paayan rẹpẹtẹ n’Igangan, nipinlẹ Ọyọ, ni wọn tun pa awọn t’Imẹkọ yii naa lẹyin ti wọn sa kuro l’Ọyọọ, ti wọn si wọle sipinlẹ Ogun.

Awọn eeyan mẹta to ku iku ojiji naa ni Fẹmi Bara, John Taiwo ati Tunde Taiwo.

ALAROYE gbọ pe awọn ọkunrin mẹta yii wa lori ọkada Bajaj tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ra ni lasiko ti wọn kagbako naa. Oko wọn ni wọn ti n bọ, wọn si n pada s’Imẹkọ ti wọn n gbe ni ki wọn too ko sọwọ awọn Fulani ọhun. Bi wọn ṣe dumbu wọn tan ni wọn tun gbe ọkada wọn lọ.

Balogun Imẹkọ-Isalẹ, Oloye Ganiu Akinlẹyẹ, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn akọroyin niluu Abẹokuta, ṣalaye pe nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ Sannde naa niṣẹlẹ yii waye.

O tẹsiwaju pe awọn Fulani apaayan yii ti tẹdo sibi kan ti wọn n pe ni Sagada, n’Imẹkọ. Balogun sọ pe aarọ Mọnde lawọn ọlọpaa waa ko oku awọn mẹta to doloogbe naa lọ si mọṣuari ileewosan Imẹkọ.

‘Awọn darandaran to sa kuro n’Igangan lẹyin ti wọn paayan ti wa labule Sagada, nipinlẹ Ogun. Oke Agbẹdẹ gan-an nibi ti wọn wa, ni wọọdu keji.

‘Odo kan wa ta a n pe ni Ọyan, laarin Sagada ati Igangan lo wa, wọn wa nibẹ bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii. A ti sọ fawọn agbofinro to yẹ ka sọ fun, ṣugbọn a ko ti i ri i ki wọn gbe igbesẹ rere kan lori ẹ.’ Bẹẹ ni Balogun Imẹkọ-Isalẹ wi.

Awọn araalu paapaa sọrọ, wọn fẹdun ọkan ṣalaye pe ẹmi awọn ko de, nitori igbakigba lawọn Fulani n daamu awọn ti wọn n pa awọn bii ẹran.

Awọn araalu sọ pe ọga ọlọpaa tẹlẹ to ni kawọn maa ko ibọn awọn waa funjọba lo ko awọn si wahala yii, nitori nigba ti wọn ti gba awọn ibọn atawọn nnkan ija awọn yooku pe kalaafia le wa lawọn ko ti ni nnkan igbara ẹni silẹ mọ.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. Ṣugbọn o ni eeyan ko le sọ pe Fulani lawọn to pa awọn to ku n’Imẹkọ yii, nitori ọkada awọn oloogbe naa ti wọn tun gbe sa lọ lẹyin ti wọn pa wọn si ni.

Oyeyẹmi sọ pe adigunjale lawọn to pa wọn naa yoo fẹrẹ jẹ. O ni ikọ alaabo tijọba Ogun ṣẹṣẹ gbe kalẹ yoo yanju ọrọ yii, wọn yoo wa awọn to ṣiṣẹ ibi naa ri,wọn yoo si ri i pe wọn gba ọkada naa pada ki wọn ma baa tun lọọ maa fi ṣiṣẹ ibi kiri.

Leave a Reply