Wọn lawọn obi yoo maa tọwọ bọwe adehun alaafia lori awọn akekọọ girama l’Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Nitori awọn iwa janduku ati jagidijagan tawọn akẹkọọ ileewe girama kan n hu nipinlẹ Ogun, Kọmiṣanna fun eto ẹkọ, sayẹnsi ati imọ-ẹrọ nipinlẹ yii, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, ti sọ pe awọn obi to lọmọ nileewe ijọba nipinlẹ Ogun yoo ni lati maa waa tọwọ bọwe adehun bayii, ti wọn yoo jẹjẹẹ pe ọmọ awọn yoo fọwọ sibi tọwọ n gbe.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, ni Ọjọgbọn Arigbabu sọrọ yii lasiko to n sọrọ lori aba iṣuna ọdun 2022 fun ipinlẹ Ogun, iyẹn nileegbimọ aṣofin ipinlẹ ọhun.

Kọmiṣanna yii tẹsiwaju pe igbẹsẹ yii waye lati kapa awọn iwakiwa bii ṣiṣe ẹgbẹ okunkun nileewe girama, ṣiṣe janduku ati bẹẹ bẹẹ lọ. O ni bi yoo ti wulo nileewe naa ni yoo tun mu alaafia ba awujọ wa.

O fi kun un pe ijọba ti tun ṣokoto san lori gbigbogun ti iwakiwa to fẹẹ gbilẹ laarin awọn akẹkọọ tọjọ ori wọn ko ti i to nnkan yii, wọn yoo si ri i pe gbogbo iwa ipanle kasẹ nilẹ patapata.

Yatọ si tawọn obi ti yoo tọwọ bọwe adehun alaafia, Ọjọgbọn Arigbabu sọ pe awọn ilana mi-in tun ti wa tijọba ti n ṣiṣẹ lori ẹ, ti wọn yoo si bẹrẹ si i mu lo laipẹ yii, ti ko fi ni i si jagidijagan nileewe ijọba mọ.

 

O ni igbimọ kan ti wa to n ṣe akọsilẹ ihuwasi awọn akẹkọọ naa, ohun ti kaluku n ṣe n wọ iwe, wọn yoo ṣi i fun un bo ṣe yẹ nigba tasiko ba to.

Bakan naa lo ni awọn ohun mi-in tawọn akẹkọọ le maa ṣe bii ere idaraya atawọn ẹkọ to yatọ si tinu kilaasi nijọba ti n mura si bayii, to bẹẹ to jẹ ọwọ awọn ọmọde naa ko ni i dilẹ, wọn ko si ni i ronu jagidijagan.

Awọn olori ileewe paapaa yoo gba ironilagbara si i gẹgẹ bi kọmiṣanna ṣe wi, ohun ti wọn nilo lati dari awọn akẹkọọ yii ko si ni i jẹ wọn niya.

 

Leave a Reply