Wọn lawọn to n beere fun Orilẹ-ede Yoruba ṣi ‘bọda’ tijọba ti n’Idiroko

Lọjọ Satide ni, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2021, niṣe lode ro n’Idiroko, nijọba ibilẹ Ipokia, nipinlẹ Ogun, nigba ti wọn ni awọn ajijgbara to n beere idasilẹ Orilẹ-ede Yoruba, ṣi bọda tijọba Buhari ti ti latọdun 2019 silẹ, ti wọn ni irẹjẹ gbaa ni bi wọn ṣe fi tilẹ Hausa silẹ lai ti, to jẹ ti Yoruba ni wọn ti pa.

Rogbodiyan ọhun pọ gẹgẹ ba a ṣe gbọ, to bẹẹ ti wọn ni awọn ajijagbara naa gba ibọn lọwọ ọkan ninu awọn agbofinro to wa nibẹ, ti wọn si fẹrẹ fi lilu ba aye ọmọkunrin kan to n ya fidio wọn jẹ.

Ninu fidio kan to wa lori ayelujara nipa iṣẹlẹ yii, kedere lo han bayii nigba tawọn ajijagbara naa gba ibọn lọwọ oṣiṣẹ Imigireṣan kan, iyẹn awọn to n ri si iwọle ati ijade awọn arinrin-ajo.

Koda, wọn ni awọn ajijagbara yii kọ lu awọn aṣọbode to fẹẹ di wọn lọwọ lati ma ṣi bọda ọhun, wọn si pada ṣi i naa ni.

Niṣe ni wọn bẹrẹ si i yinbọn soke, ti wọn ba geeti to wa lẹnu ọna bọda naa jẹ, ti wọn n sọ pe kawọn ṣọja jade o, atawọn agbofinro yooku, ki wọn waa yinbọn o. Koda, wọn sọ fawọn eeyan to wa nibẹ pe ki wọn bẹrẹ kara-kata wọn pada, ki wọn maa ko ọja wọle lati Benin, ki wọn si maa ko ti Naijiria naa jade.

Alukoro Kọstọọmu nipinlẹ Ogun, iyẹn ẹkun akọkọ, Ọgbẹni Hammed Oloyede, sọ pe loootọ lawọn ajijagbara naa gbiyanju awọn nnkan wọnyi, o ni ṣugbọn wọn ko kọ lu oṣiṣẹ awọn kankan, nitori awọn tete kapa ẹ.

Oloyede sọ pe awọn eeyan naa ko kọ lu ikọ kọsitọọmu to n ṣọde kiri, wọn ko si de awọn ibi tawọn ti n da awọn ọkọ duro lati yẹ wọn wo.

O lawọn to n beere Ilẹ Olominira Yoruba naa n ṣe tiwọn ni, wọn ko di awọn lọwọ.

Awọn ọmọ ẹyin ajafẹtọọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ (Igboho) ni awọn eeyan ti wọn ni wọn ṣi bọda kalẹ yii, niṣe ni wọn si n fi igboya sọrọ ninu fidio ti wọn ṣe, ti wọn ni irẹjẹ ti to, awọn ko fẹ Naijiria mọ, Orilẹ-ede Yoruba lawọn n ba lọ.

Ẹ oo ranti pe Igboho funra ẹ ti figba kan sọ ọ ninu fidio kan pe gbogbo bọda ilẹ Yoruba ti wọn ti lawọn yoo ṣi silẹ pata, ti ounjẹ yoo maa wọle daadaa ti ko si ni i si irẹjẹ ti wọn n foju awọn Yoruba ri ni Naijiria mọ.

Ijọba ibilẹ Ipokia, ni ilu ti wọn n pe n’Idiroko yii wa, aala Naijiria si Orilẹ-ede Olominira Benin lo wa, ohun to jẹ ki bọda wa nibẹ niyẹn.

Leave a Reply