Wọn le ọmọ ileegbimọ aṣofin danu ninu APC l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹgbẹ oṣelu APC  nijọba ibilẹ Ilajẹ ti yọ ọkan ninu awọn aṣofin to n ṣoju agbegbe ọhun nileigbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Tomowewo Favour, lori ẹsun siṣe ohun to lodi sofin ẹgbẹ.

Alaga ẹgbẹ APC wọọdu kẹrin niluu Mahin, Ọgbẹni Ọlagoke Ajimuda, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu lẹta iyọni lẹgbẹ ti wọn fi ṣọwọ sì Ọnarebu ọhun l’Ọjọruu, Wẹsidee ọsẹ yii.

Ọnarebu Tomowewo ni obinrin kan soso to wa laarin awọn aṣofin mẹrindinlọgbọn to wa nile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, o si wa lara awọn ti wọn jawee gbele-ẹ fun lori bi wọn ṣe kọ lati buwọ lu iwe iyọninipo Igbakeji Gomina, Agboọla Ajayi, ni nnkan bii osu meji sẹyin.

Leave a Reply