Faith Adebọla, Eko
Eeyan mẹta lo dagbere faye nigba ti ọkọ oju omi akero kan doju de nitosi Imoba, lagbegbe Ajido, ni Badagry, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Ba a ṣe gbọ, wọn lẹnjinni ọkọ ayara-bii-aṣa lo ṣadeede daṣẹ silẹ lori ere, niṣe lo pana lojiji, ọkọ oju omi naa si doju de.
Abilekọ Nkechi Ajayi to jẹ Alukoro LASWA, iyẹn ileeṣẹ ọkọ oju omi ipinlẹ Eko, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni lati agbegbe Liverpool, l’Ekoo, ni ọkọ naa ti gbera, ki iṣẹlẹ ibanujẹ naa too waye.
Eeyan mẹtadinlogun la gbọ pe awọn ọlọpaa to n pese aabo lori omi doola ẹmi wọn ninu ijamba naa, nigba tawọn mẹta ku somi.
Ajayi ni ọmọde mẹta wa ninu awọn ti wọn ri fa yọ naa, wọn si ti ko gbogbo wọn lọ sọsibitu Jẹnẹra Badagry, fun itọju.
Bakan naa lawọn ọlọpaa oju-oju (marine police) ti ko oku awọn to doloogbe lọ si mọṣuari, awọn mọlẹbi wọn si ti n tọwọ bọwe lati gba iyọnda oku naa, ki wọn le lọọ si wọn.
Ajayi ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii lati mọ pato ohun to mu ki ẹnjinni naa yọwọ lori ere, o si kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi ti wọn padanu eeyan wọn.