Wọn lọmọbinrin yii lọọ ṣere fawọn ọlọjọọbi leti okun Eko, lo ba ku somi

Faith Adebọla, Eko

 Ọdọmọbinrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Michelle Abẹṣin, oṣere to n ṣiṣẹ DJ lode ariya, ti pade iku ojiji nibi ariya ọjọọbi kan to lọọ ṣere fun wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, niṣe lo ri somi letikun, lo si ṣe bẹẹ doloogbe.

Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o waye nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, letikun Lẹkki Beach, lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko.

Wọn ni ọkan lara awọn mọlẹbi ọmọbinrin yii lo fẹẹ ṣayẹyẹ ọjọọbi ẹ, Lẹkki Beach yii ni wọn dana ariya ọhun si, ti oloogbe naa fi si n ba wọn gbe orin aladun ọlọkan-o-jọkan si i, gẹgẹ bii iṣẹ rẹ.

Wọn lawọn ọrẹ ọlọjọọbi kan ni wọn ni kawọn lọọ ya fọto ati fidio ninu alagbalugbu omi okun ki kinni naa le tubọ larinrin, DJ Michelle si ba wọn lọ, ṣugbọn omi okun ti ki i figba kan parọrọ lo n ru bọ bo ṣe maa n ṣe, igbi omi naa si lagbara debi to fẹẹ gba foonu ti wọn fi n ya fidio, koloju too ṣẹju, wọn lọmọbinrin to doloogbe yii ṣubu somi, ko si ṣee ṣe fawọn to ku lati fa a jade, ki igbi omi mi-in too kan wọn lara, ni Michelle ba ri somi.

Titi dasiko yii, wọn o ti i ri oku rẹ fa jade, bo tilẹ jẹ pe awọn pẹjapẹja kan ti n ṣiṣẹ lati ba wọn wa oku ọhun.

Aburo oloogbe naa, Stella Abesin, kọ ọrọ aro nipa ẹgbọn rẹ sori ikanni Instagiraamu rẹ, pe: “Eyi o tọ si ẹgbọn mi o, ha, mi o le mi mọ. Gbogbo wọn waa n woran bi omi okun ṣe gbe ẹgbọn mi lọ, Ọlọrun Ọba o, nibo larabinrin mi wa. Nibo ni oku ẹ wa?”

Bẹẹ naa lawọn ọrẹ ati ololufẹ oloogbe naa fi iyalẹnu wọn han si iku airotẹlẹ rẹ yii, wọn si ṣedaro ẹ loriṣiiriṣii, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, akọyinsi ẹni to ku ki i gbọ oriki.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, CSP Adekunle Ajiṣebutu, ko ti i fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, tori ko fesi si ipe ta a pe e ati atẹjiṣẹ ta a fi ṣọwọ si i.

Leave a Reply