Wọn loore lọkunrin to ṣegbeyawo pẹlu obinrin mẹrin lọjọ kan ṣoṣo ṣe fun wọn

Ko ṣẹlẹ ri kan ko si, ohun to ba ti waye ti dohun ti aye ri ri naa niyẹn. Ohun tawọn eeyan n sọ lori ayelujara ree latigba ti aworan ọkunrin ọmọ ilẹ Gabon to ṣegbeyawo pẹlu obinrin mẹrin lọjọ kan ṣoṣo ti gori atẹ.

Kinni ọhun ko tiẹ jọ awọn mi-in loju, wọn ni olowo ni ọkọ iyawo naa torukọ ẹ n jẹ Mesmine Abessole.

Oniṣowo pataki ni wọn mọ ọn si ni Gabon, wọn ni buruku owo wa lọwọ ẹ, bawo waa ni yoo ṣe maa jọọyan loju pe olowo ṣe ohun gbogbo tan.

Lọjọ ti oṣu keje pari gan-an, iyẹn ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun 2021, ni ọkunrin ti wọn n pe ni Abessole yii da ara nla, lọjọ naa lo gbe awọn obinrin mẹrin niyawo, orukọ wọn ni: Madeleine Nguema, Prisca Nguema, Nicole Mboungou ati Carene Sylvana Aboghet.

Ibi kan ti wọn n pe ni Libreville, ni Gabon, layẹyẹ igbeyawo naa ti waye.

Pasitọ lo so wọn pọ, ko si ẹnikan to ta ko isopọ yii, wọn ko si ka a nibẹ pe ọkunrin kan, obinrin kan ni wọn gbọdọ jọ ṣegbeyawo, bo tilẹ jẹ pe ilana Kristẹni naa ni wọn fi so wọn pọ.

Nigba to tiẹ jẹ muṣẹ lawọn iyawo n rẹrin-in, ti ọkọ paapaa n fo fayọ, to duro laarin wọn pẹlu idunnu, ko sẹni kan ti isopọ naa ṣe ajeji lara rẹ ninu awọn to waa ba wọn ṣe e. To ba si ṣajoji, wọn ko sọ ọ jade.

Kaka bẹẹ, kaluku n sọ pe àrà ni baba olowo yii fi da ni, wọn ni ẹni to ba to nnkan nla i ṣe naa lo n ṣe iru eyi lawujọ.

Awọn eeyan mi-in koro oju si isopọ yii ṣa, wọn ni ko tọna.

Ṣugbọn awọn kan sọ pe laye ti obinrin pọ ju ọkunrin lọ yii, ko sohun to buru nibẹ, oore lọkunrin olowo naa ṣe fawọn obinrin to fẹ jare.

Leave a Reply