Wọn lu Wasiu lalubami, igbọnṣẹ awọn eeyan lo n ko tọwọ fi tẹ ẹ l’Ẹdẹ  

Florence Babaṣọla

Alubami lawọn ọmọleewe Muslim Grammar School, niluu Ẹdẹ, lu ọmọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Wasiu Ọlaṣukomi, lọjọ Ẹti, Furaidee, to lọ yii, lasiko ti wọn ka a mọbi to ti n ko igbọnsẹ gbigbẹ sinu apo.

Agbegbe ileewe naa la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ laago mẹwaa aabọ aarọ. Bi awọn akẹkọọ si ṣe ri i lọọọkan ni wọn ya bo o, ti wọn si bẹrẹ si i lu u bii bẹmbẹ.

Biṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ lawọn ọlọpaa ti wọn n lọ kaakiri debẹ, ṣugbọn ṣe lawọn akẹkọọ naa n ju wọn lokuta lasiko ti wọn n gbiyanju lati gba Wasiu silẹ lọwọ wọn.

Koda, awọn olukọ ti wọn yọju sibẹ ko faraare lọ, nitori ṣe lawọn akẹkọọ naa fi okuta sin wọn pada sinu yara ikẹkọọ ti wọn ti wa.

Idi niyẹn tawọn ọlọpaa fi pe fun awọn ẹgbẹ wọn diẹ si i, nigba ti wọn si de lagbara too ka awọn akẹkọọ naa, ti wọn si sa lọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe loootọ ni, ati pe awọn afurasi marun-un lọwọ ti tẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ọpalọla sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori ẹsun ti wọn fi kan afurasi naa.

 

Leave a Reply